Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 8:2-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ísírẹ́lì kígbe pè mí‘Áà! Ọlọ́run wa, àwa mọ̀ ọ́!’

3. Ṣùgbọ́n Ísírẹ́lì ti kọ ohun tí ó dára sílẹ̀ọ̀tá yóò sì máa lépa rẹ̀

4. Wọ́n fi àwọn ọba jẹ ṣùgbọ́n, kì í ṣe nípasẹ̀ miwọ́n yan ọmọ aládé láì si ìmọ̀ mi nibẹ̀.Wọ́n fi fàdákà àti wúràṣe ère fún ara wọn,kì a ba le ké wọn kúrò.

5. Ọmọ-mààlu rẹ ti ta ọ́ nù ìwọ Ṣamáríà! Ju ère tí o gbẹ́ nùÌbínú mi ń ru sí wọn:yóò ti pẹ́ tó kí wọ́n tó dé ipò àìmọ̀kan?

6. Ísírẹ́lì ni wọ́n ti wá!Ère yìí—agbẹ́gilére ló ṣe éÀní ère Samáríà, ni a ó fọ́ sí wẹ́wẹ́.

Ka pipe ipin Hósíà 8