Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 8:10-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti ta ara wọn sí àárin orílẹ̀ èdèÈmi ó ṣà wọ́n jọ nísinsìn yìíWọn ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣòfò dànùlọ́wọ́ ìnílára ọba alágbára.

11. “Nítorí Éfúráímù ti kọ́ pẹpẹ púpọ̀ fún ìrúbọ ẹ̀ṣẹ̀gbogbo rẹ̀ ti di pẹpẹ ìdẹ́ṣẹ̀ fún un

12. Mo kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí ó jẹ́ òfin mi fún wọn.Ṣùgbọ́n wọn kà á sí ohun àjèjì

13. Wọ́n ń rúbọ tí wọ́n yàn fún mi,wọ́n sì ń jẹ ẹran ibẹ̀Ṣùgbọ́n inú Olúwa kò dùn sí wọn.Báyìí yóò rántí ìwà búburú wọnyóò sì jẹ wọ́n níyà fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.Wọn yóò padà sí Éjíbítì

14. Nítorí Ísírẹ́lì ti gbàgbé ẹlẹ́dàá rẹ̀Ó sì ń kọ́ ààfin púpọ̀Júdà ti kọ́ ìlú olódi púpọ̀ṣùgbọ́n èmi ó rán iná kansí orí àwọn ìlú rẹ̀ èyí tí yóò jẹ ibi agbára rẹ̀ run.”

Ka pipe ipin Hósíà 8