Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 7:2-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ pémo rántí gbogbo ìwà búburú wọn:Ẹ̀ṣẹ̀ wọn gbé wọn mì pátapátawọ́n wà níwájú mi nígbà gbogbo.

3. “Wọ́n ń mú inú ọba dùn pẹ̀lú ìwà búburú wọn,àti inú ọmọ aládé dùn pẹ̀lú irọ́ wọn

4. Alágbèrè ni gbogbo wọnwọ́n gbóná bí ààrò àkàràtí o dáwọ́ kíkọná dúró, lẹ́yìnìgbà tí o ti pò iyẹ̀fun tán, títí ìgbà tí yóò wú.

5. Ní ọjọ́ àjọ̀dún ọba wawáìnì mú ara àwọn ọmọ aládé gbónáó sì darapọ̀ mọ́ àwọn oníyẹ̀yẹ́.

Ka pipe ipin Hósíà 7