Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 7:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí èmi ìbá mú Ísírẹ́lì láradá.Ẹ̀ṣẹ̀ Éfúráímù ń farahànìwà búburú Ṣamáríà sì ń hàn sítaWọ́n ń ṣe èrúàwọn olè ń fọ́ iléàwọn ọlọ́ṣà ń jalè ní òpópónà

2. Ṣùgbọ́n wọn kò mọ̀ pémo rántí gbogbo ìwà búburú wọn:Ẹ̀ṣẹ̀ wọn gbé wọn mì pátapátawọ́n wà níwájú mi nígbà gbogbo.

3. “Wọ́n ń mú inú ọba dùn pẹ̀lú ìwà búburú wọn,àti inú ọmọ aládé dùn pẹ̀lú irọ́ wọn

4. Alágbèrè ni gbogbo wọnwọ́n gbóná bí ààrò àkàràtí o dáwọ́ kíkọná dúró, lẹ́yìnìgbà tí o ti pò iyẹ̀fun tán, títí ìgbà tí yóò wú.

5. Ní ọjọ́ àjọ̀dún ọba wawáìnì mú ara àwọn ọmọ aládé gbónáó sì darapọ̀ mọ́ àwọn oníyẹ̀yẹ́.

6. Ọkàn wọn ń gbóná bí i ààròwọ́n sì tọ̀ ọ́ lọ pẹ̀lú rìkísí,ìbínú wọn pa lọ́lọ́ ní gbogbo òruó sì bú jáde bí ọ̀wọ́ iná ní òwúrọ̀.

Ka pipe ipin Hósíà 7