Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 6:5-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Nítorí náà ni mo ṣe gé e yín sí wẹ́wẹ́ láti ọwọ́ àwọn wòlíì.Mo pa yín pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹnu miÌdájọ́ mi tàn bí i mọ̀nàmọ́ná lórí yín

6. Nítorí pé mo fẹ́ àánú, kì í ṣe ẹbọ;àti ìmọ́ Ọlọ́run ju ọrẹ ẹbọ sísun lọ.

7. Bí i Ádámù, wọ́n da májẹ̀múwọ́n jẹ́ aláìsòótọ́ sí mi níbẹ̀.

8. Gílíádì jẹ́ ìlú àwọn ènìyàn búburútí ń ṣiṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, a sí ti fi ẹ̀ṣẹ̀ bà á jẹ́.

9. Bí adigunjalè ṣe ń ba ní bùbá de àwọn ènìyànbẹ́ẹ̀ ni àwọn àlùfáà, ń parapọ̀;tí wọ́n sì ń pànìyàn lójú ọ̀nà tó lọ sí Ṣékémù,tí wọ́n sì ń dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ti ni lójú.

10. Mo ti rí ohun tó bani lẹ́rùní ilé Ísírẹ́lì.Níbẹ̀ Éfúráímù, fi ara rẹ̀ fún àgbèrèÍsírẹ́lì sì di aláìmọ́.

11. “Àti fún ìwọ, JúdàA ti yan ọjọ́ pẹ̀lú ìkórè rẹ“Nígbà tí mo bá fẹ́ dá ohun ìní àwọn ènìyàn mi padà,

Ka pipe ipin Hósíà 6