Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 5:9-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

9. Éfúráímù yóò di ahoroní ọjọ́ ìbáwíláàrin àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lìMo sọ ohun tí ó dájú.

10. Àwọn olórí Júdà dàbí àwọn tí ímáa yí òkúta ààlà kúrò.Èmi ó tú ìbínú gbígbóná mi léwọn lórí bí ìkún omi.

11. A ni Éfúráímù lára,A sì tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ ní ìdájọ́nítorí pé, ó pinnu láti tẹ̀lé òrìṣà

12. Mo dàbí kòkòrò aṣọ sí ÉfúráímùMo sì dàbí ìdin sí ara Júdà.

13. “Nígbà ti Éfúráímù ri àìsàn rẹ̀,tí Júdà sì rí ojú egbò rẹ̀ni Éfúráímù bá tọ ará Síríà lọ,ó sì ránṣẹ́ sí ọba ńlá náà fún ìrànlọ́wọ́ṣùgbọ́n kò le è wò ó sànbẹ́ẹ̀ ni kò le wo ojú egbò rẹ̀ jinná

14. Nítorí pé, èmi ó dàbí kìnnìún sí Éfúráímù,bí i kìnnìún ńlá sí ilé Júdà.Èmi ó fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ èmi ó sì lọ;Èmi ó gbé wọn lọ, láì sí ẹni tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀.

15. Nígbà náà ni èmi ó padà lọ sí ààyè mitítí di ìgbà tí wọn ó fi gbà pé àwọn jẹ̀biwọn yóò sì wá ojú minínú ìpọ́njú wọn, wọn ó fi ìtara wá mi.”

Ka pipe ipin Hósíà 5