Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 5:12-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Mo dàbí kòkòrò aṣọ sí ÉfúráímùMo sì dàbí ìdin sí ara Júdà.

13. “Nígbà ti Éfúráímù ri àìsàn rẹ̀,tí Júdà sì rí ojú egbò rẹ̀ni Éfúráímù bá tọ ará Síríà lọ,ó sì ránṣẹ́ sí ọba ńlá náà fún ìrànlọ́wọ́ṣùgbọ́n kò le è wò ó sànbẹ́ẹ̀ ni kò le wo ojú egbò rẹ̀ jinná

14. Nítorí pé, èmi ó dàbí kìnnìún sí Éfúráímù,bí i kìnnìún ńlá sí ilé Júdà.Èmi ó fà wọ́n ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ èmi ó sì lọ;Èmi ó gbé wọn lọ, láì sí ẹni tí yóò gbà wọ́n sílẹ̀.

15. Nígbà náà ni èmi ó padà lọ sí ààyè mitítí di ìgbà tí wọn ó fi gbà pé àwọn jẹ̀biwọn yóò sì wá ojú minínú ìpọ́njú wọn, wọn ó fi ìtara wá mi.”

Ka pipe ipin Hósíà 5