Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 4:7-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

7. Bí àwọn àlùfáà ṣe ń pọ̀ sí ibẹ́ẹ̀ ni wọ́n ṣe ń dẹ́ṣẹ̀ sí mi.Wọ́n yí ògo mi padà sí ohun ìtìjú

8. Wọ́n ń jẹun nípa ẹ̀sẹ̀ àwọn ènìyàn miWọ́n sì ń gbádùn nínú ìwà búburú wọn.

9. Yóò wá ṣe gẹ́gẹ́: bí ènìyàn ṣe rí náà ni àwọn àlùfáà ríÈmi ó jẹ gbogbo wọn níyà nítorí ọ̀nà wọn.Èmi ó sì san án fún wọn gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn.

10. “Wọn ó máa jẹun ṣùgbọ́n wọn kò ní yó;Wọn ó ṣe àgbèrè ṣùgbọ́n, wọn kò ni pọ̀ sí i,nítorí pé wọ́n ti kọ Olúwasílẹ̀

11. ‘Wọ́n sì ti fi ara wọn’ fún àgbèrè,wọ́n fi ara wọn fún wáìnì àtijọ́àti tuntun èyí tó gba òye àwọn ènìyàn mi sọnù

Ka pipe ipin Hósíà 4