Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hósíà 4:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa ẹ̀yin ọmọ Ísírẹ́lì,nítorí pé Olúwa fi ẹ̀sùnkan ẹ̀yin tí ń gbé ní ilẹ̀ náà.“Kò sí ìwà òtítọ́, kò sí ìfẹ́Kò sí ìmọ̀ Ọlọ́run ní ilẹ̀ náà

2. Afi èpè, irọ́ pípa àti ìpànìyànolè jíjà àti panṣágà.Wọ́n rú gbogbo òfin,ìtàjẹ̀sílẹ̀ sì ń gorí ìtàjẹ̀sílẹ̀.

3. “Nítorí èyí, ilẹ̀ náà ń ṣọ̀fọ̀, gbogboolùgbé ibẹ̀ sì ń ṣòfò dànù.Ẹranko igbó àti ẹyẹ ojú ọ̀runàti ẹja inú omi ló ń kú.

4. “Ṣùgbọ́n kí ẹnikẹ́ni má ṣe mú ẹ̀sùn wá,kí ẹnìkan má sì ṣe fi ẹ̀sùn kan ẹ̀nìkéjìnítorí àwọn ènìyàn rẹ̀ dàbíàwọn ti ń fi ẹ̀sùn kan àlùfáà

Ka pipe ipin Hósíà 4