Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hágáì 1:6-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ẹ̀yin ti gbìn ohun ti ó pọ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kórè díẹ̀ níbẹ̀; Ẹ̀yin jẹun, Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò yó. Ẹ̀yin mu ṣùgbọ́n kò tẹ́ ẹ yín lọ́run; ẹ̀yin wọ aṣọ, ṣùgbọ́n kò mú òtútù yin lọ; Ẹ̀yin gba owó iṣẹ́ ṣùgbọ́n ẹ ń gbà á sínú ajádìí àpò.”

7. Báyìí ni Olúwa alágbára wí: “Ẹ kíyèsi ọ̀nà yín.

8. Ẹ gun orí àwọn òkè ńlá lọ, kí ẹ sì mú igi wá pẹ̀lú yín. Kí ẹ sì kọ́ ilé náà, kí inú mi bà leè dùn sí i, kí a sì yín mí lógo,” ni Olúwa wí.

9. “Ẹyin ti ń retí ọ̀pọ̀, ṣùgbọ́n kíyèsíi,, o yípadà sí díẹ̀. Ohun tí ẹ̀yin mú wa ilé, èmi sì fẹ́ ẹ dànù. Nítorí kí ni?” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. “Nítorí ilé mi tí ó dáhoro; tí olúkúlùkù yín sì ń sáré fún ilé ara rẹ̀.

10. Nítorí yín ni awọn ọ̀run ṣe dá ìrì dúró tí ilẹ̀ sì kọ̀ láti mu èso jáde.

11. Mo sì ti pe ọ̀dá sórí ilẹ̀ àti sórí awọn òkè-ńlá, sórí ọkà àti sórí wáìnì tuntun, sórí òróró àti sórí ohun ti ilẹ̀ ń mú jáde, sórí ènìyàn, sórí ẹran àti sórí gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ yín.”

Ka pipe ipin Hágáì 1