Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hágáì 1:13-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Nígbà náà ni Hágáì ìránṣẹ́ Olúwa ń jíṣẹ́ Olúwa fún àwọn ènìyàn pé, “Èmí wà pẹ̀lú yín,” ni Olúwa wí.

14. Nítorí náà, Olúwa ru ẹ̀mí Sérúbábẹ́lì ọmọ Séítélì sókè, olórí Júdà àti ẹ̀mí Jóṣúà ọmọ Jósédékì, olórí àlùfáà àti ẹ̀mí gbogbo ènìyàn ìyókù. Wọ́n sì wá, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣiṣẹ́ lórí ilé Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run wọn,

15. ní ọjọ́ kẹrìnlélógún oṣù kẹfà ní ọdún kejì ọba Dáríúsì.

Ka pipe ipin Hágáì 1