Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hábákúkù 3:4-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Dídán rẹ ṣí dàbí ìmọ́lẹ̀;Ìmọ́lẹ̀ kọ-ṣàn-án láti ọwọ́ rẹ wá,níbi tí wọn fi agbára rẹ̀ pamọ́ sí.

5. Àjàkálẹ̀ àrùn ń lọ ni iwájú rẹ;ìyọnu ṣí ń tọ ẹsẹ̀ rẹ lọ.

6. Ó dúró, ó sì mi ayé;ó wò, ó sì mú àwọn orílẹ̀-èdè wárìrìa sì tú àwọn òkè-ńlá ayérayé ká,àwọn òkè kéékèèkéé ayérayé sì tẹríba:ọ̀nà rẹ ayérayé ni.

7. Mo rí àgọ́ Kúṣánì nínú ìpọ́njúàti àwọn ibùgbé Mídíanì nínú ìrora.

8. Ǹjẹ́ ìwọ ha ń bínú sí àwọn Odò nì, Olúwa?Ǹjẹ́ ìbínú rẹ wa lórí àwọn odò síṣàn bí?Ìbínú rẹ ha wá sórí òkuntí ìwọ fi ń gún ẹṣin,àti kẹ̀kẹ́ ìgbàlá rẹ?

9. Ìwọ kò bo ọrun rẹ,o sì pè fún ọ̀pọ̀lọ́pọ̀ ọfàìwọ sì pín ayé níyà pẹ̀lú odò.

10. Àwọn òkè-ńlá ri ọ wọn ṣì wárìrìàgbàrá òjò ń ṣàn án kọjá lọ;ibú ń ké ramúramùó sì gbé irú omi sókè.

Ka pipe ipin Hábákúkù 3