Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Hábákúkù 3:15-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ìwọ fi ẹṣin rẹ rìn òkun já,O tẹ òkun mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ẹṣin rẹ̀,ìwọ fi àwọn ẹsin rẹ̀ rin òkun já,ó sì mu omi ńlá jáde okiki omi ńlá

16. Mo gbọ́, ọkàn mi sì wárìrì,ètè mi sì gbọ̀n sí ìró náà;ìbàjẹ́ sì wọ inú egungun mi lọ,ẹ̀sẹ̀ mi sì wárìrì,mo dúró ni ìdákẹ́jẹ́ fún ọjọ́ ìdààmúláti de sórí àwọn ènìyàn tó ń dojúkọ wá.

17. Bí igi ọ̀pọ̀tọ́ ko tilẹ̀ tanná,tí èso kò sí nínú àjàrà;tí iṣẹ igi olifi yóò jẹ́ àṣedànù,àwọn oko ki yóò sì mú oúnjẹ wá;tí a ṣi ke agbo ẹran kúrò nínú agbo,tí ki yóò sì sí ọwọ́ ẹran ni ibùsọ̀ mọ́,

18. ṣùgbọ́n ṣíbẹ̀, èmi o layọ nínú Olúwaèmi yóò sí máa yọ nińú Ọlọ́run ìgbàla mi.

19. Olúwa Ọlọ́run ni agbára mi,òun yóò sí ṣe ẹsẹ̀ mi bí ẹsẹ̀ àgbọ̀nrín,yóò sí mú mi rìn lórí ibi gíga.Ṣi olórí akọrin lórí ohun èlò orin olókùn mi.

Ka pipe ipin Hábákúkù 3