Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sítà 5:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọjọ́ kẹta Ẹ́sítà wọ aṣọ ayaba rẹ̀ ó sì dúró sí inú àgbàlá ààfin, ní iwájúu gbọ̀ngàn ọba, ọba Jókòó lórí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ nínú un gbọ̀ngàn, ó kọjú sí ẹnu ọ̀nà ìta.

2. Nígbà tí ó rí ayaba Ẹ́sítà tí ó dúró nínú àgbàlá, inú un rẹ̀ yọ́ síi, ó sì na ọ̀pá aládé wúrà ọwọ́ọ rẹ̀ sí i. Bẹ́ẹ̀ ni Ẹ́sítà ṣe ṣún mọ́ ọn ó sì fi ọwọ́ kan orí ọ̀pá náà.

3. Nígbà náà ni ọba béèrè pé, “kí ni ó dé, ayaba Ẹ́sítà? Kí ni o fẹ́? Bí ó tilẹ̀ ṣe títí dé ìdajìn mi ìjọba àní, a ó fi fún ọ.”

4. Ẹ́sítà sì dáhùn pé, “Bí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn, jẹ́ kí ọba, pẹ̀lúu Hámánì, wá lónìí sí ibi àṣè tí èmi ti pèṣè fún-un.”

Ka pipe ipin Ẹ́sítà 5