Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sírà 8:22-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Mo tijú láti béèrè lọ́wọ́ ọba fún àwọn jagunjagun orí ilẹ̀, àti ti orí ẹsin láti dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá ní ọ̀nà wa, nítorí àti sọ fún ọba pé, “Ọwọ́ àánú Ọlọ́run wà ní ara gbogbo ẹni tí ó gbé ojú sókè sí i, ṣùgbọ́n ìbìnú ńlá rẹ wà lórí ẹni tó kọ̀ sílẹ̀.”

23. Bẹ́ẹ̀ ni a sì gbààwẹ̀, a sì bẹ̀bẹ̀ fún èyí lọ́dọ̀ Ọlọ́run wa, òun sì gbọ́ àdúrà wa.

24. Nígbà náà ni mo yà àwọn àlùfáà tó jẹ́ aṣáájú méjìlá sọ́tọ̀, pẹ̀lú Ṣérébáyà, Hásábáyà àti mẹ́wàá lára àwọn arákùnrin wọn,

25. Mo sì fi òṣùwọ̀n wọn ọrẹ fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò tí ọba àti àwọn ìgbìmọ̀, awọn ìjòyè àti gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì tí ó wà níbẹ̀ gbe fi sílẹ̀ fún ilé Ọlọ́run wa.

26. Mo fi òsùwọ̀n wọn ẹgbẹ̀talẹ̀láàdọ́ta (650) talẹ́ńtì sílifà, àti ohun èlò fàdákà tí ó wọn ọgọ́rùn ún talẹ́ńtì, talẹ́ńtì wúrà

27. ogún (20) bóòlù wúrà (kílòmítà mẹ́jọ ààbọ̀) tí iye rẹ̀ tó ẹgbẹ̀rún (1,000) dárìkì, àti ohun èlò idẹ dáradára méjì ti ó ni iye lórí, bí i wúrà.

28. Mo wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin àti àwọn ohum èlò wọ̀nyí ni a ti yà sí mímọ́ fún Olúwa. Sílífà àti wúrà sì jẹ́ ọrẹ àtinúwá sí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín.

29. Tọ́jú wọn dáradára títí ìwọ yóò se fi òṣùwọ̀n wọ̀n wọ́n jáde kúrò ni ilé Olúwa ni Jérúsálẹ́mù ní iwájú àwọn aṣáájú àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì àti ní iwájú olórí ìdílé gbogbo ni Ísírẹ́lì.”

30. Nígbà náà ni àwọn àlùfáà àti àwọn Léfì gba fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò mímọ́ ti a ti wọ̀n jáde fún kíkó lọ sí ilé Ọlọ́run wa ní Jérúsálẹ́mù.

31. Ní ọjọ́ kejìlá oṣù kìn-ín-ní ni a gbéra kúrò ní ẹ̀bá odò Áháfà láti lọ sí Jérúsálẹ́mù. Ọwọ́ Ọlọ́run wa wà lára wa, ó sì dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta àti àwọn adigunjalè ní ọ̀nà wa.

32. Bẹ́ẹ̀ ni a gúnlẹ̀ sí Jérúsálẹ́mù, nibi ti a ti sinmi fún ọjọ́ mẹ́ta.

33. Ní ọjọ́ kẹrin, a wọn ohun èlò fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò mímọ lé àlùfáà Mérémótì ọmọ Úráyà lọ́wọ́, láti inú ilé Ọlọ́run wa, Élíásérì ọmọ Fínéhásì wà pẹ̀lú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Léfì Jósábádì ọmọ Jésíúà àti Núádáyà ọmọ Bínúì wà níbẹ̀ pẹ̀lú.

34. Gbogbo nǹkan ni a kà tí a sì wọ̀n, gbogbo iye ìwọ̀n ni a sì ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀ sínú ìwé ìgbà náà.

35. Nígbà náà ni àwọn ìgbèkùn tí o ti pada láti ilẹ̀ àjèjì rú ẹbọ ọrẹ sísun sí Ọlọ́run Ísírẹ́lì: akọ màlúù méjìlá fún gbogbo Ísírẹ́lì, àádọ́rùn-ún-o-lé-mẹ́ta akọ ọdọ àgùntàn àti òbúkọ méjìlá fún ọrẹ sísun sí Olúwa.

Ka pipe ipin Ẹ́sírà 8