Níbẹ̀, ní ẹ̀bá odò Áháfà, mo kéde ààwẹ̀, kí a ba à le rẹ ara wa sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run kí a sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ fún ìrìnàjò àìléwu fún wa àti àwọn ọmọ wa àti fún gbogbo ohun ìní wa.