Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sírà 8:13-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. nínú àwọn ọmọ Ádóníkámù, àwọn ti ó gbẹ̀yìn, tì orùkọ wọn ń jẹ̀ Élífélétì, Jéúélì àti Ṣémáyà, àti ọgọ́ta (60) ọkúnrin pẹ̀lú wọn;

14. Nínú àwọn ọmọ Bígífáyì, Hútayì àti Ṣákúrì, àti àádọ́rin 70 ọkúnrin pẹ̀lú wọn.

15. Èmi kó wọn jọ pọ̀ si etí odò ti ń ṣàn lọ sí Áháfà, a pàgọ́ síbẹ̀ fùn odidi ọjọ́ mẹ́ta, nígbà ti mo wo àárin àwọn ènìyàn àti àárin àwọn àlùfáà, ń kò ri ọmọ Léfì kankan níbẹ̀.

16. Nígbà náà ni mo pe Élíásérì, Áríélì, Ṣemanáyà, Elinátanì, Járíbù, Elinátánì, Nátanì, Ṣakaráyà, àti Mésúlámù, ti wọ̀n jẹ̀ olórí, àti Jóíáríbù àti Elinátanì ti wọ̀n jẹ́ onímọ̀ ìjìnlẹ̀,

17. mo rán wọn sí Ídò, tí ó wà ní ibi ti a ń pè ni Kásífíà, mo sì sọ ohun ti wọn yóò sọ fun Ídò àti àwọn arakunrin rẹ̀ ti wọn jẹ́ òṣìṣẹ́ tẹ́ḿpìlì ní Kásífíà fún wọn, pé, kí wọn mú àwọn ìránṣẹ́ wá fún wa fún ilé Ọlọ́run wa.

18. Nítorí ọwọ́ àánú Ọlọ́run wa wà lára wa, wọ́n sì mú Ṣérébáyà wá fún wa, ẹni tí ó kún ojú òṣùwọ̀n láti ìran Máhílì ọmọ Léfì, ọmọ Ísírẹ́lì, àti àwọn ọmọ Ṣérébáyà àti àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n jẹ́ ọkùnrin méjìlélógún (18).

19. Àti Ásábáyà, pẹ̀lú Jésáíyà láti ìran Mérárì, pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ àti àwọn ọmọ wọ́n jẹ́ ogún (20) ọkùnrin.

20. Wọ́n sì tún mú ọ̀kànlénígba (220) àwọn òṣìṣẹ́ tẹ́ḿpìlì wá-àwọn ènìyàn tí Dáfídì àti àwọn ìjòyè rẹ gbé kalẹ̀ láti ràn àwọn ọmọ Léfì lọ́wọ́. Gbogbo wọn ni a ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ wọn.

21. Níbẹ̀, ní ẹ̀bá odò Áháfà, mo kéde ààwẹ̀, kí a ba à le rẹ ara wa sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run kí a sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ fún ìrìnàjò àìléwu fún wa àti àwọn ọmọ wa àti fún gbogbo ohun ìní wa.

22. Mo tijú láti béèrè lọ́wọ́ ọba fún àwọn jagunjagun orí ilẹ̀, àti ti orí ẹsin láti dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá ní ọ̀nà wa, nítorí àti sọ fún ọba pé, “Ọwọ́ àánú Ọlọ́run wà ní ara gbogbo ẹni tí ó gbé ojú sókè sí i, ṣùgbọ́n ìbìnú ńlá rẹ wà lórí ẹni tó kọ̀ sílẹ̀.”

23. Bẹ́ẹ̀ ni a sì gbààwẹ̀, a sì bẹ̀bẹ̀ fún èyí lọ́dọ̀ Ọlọ́run wa, òun sì gbọ́ àdúrà wa.

24. Nígbà náà ni mo yà àwọn àlùfáà tó jẹ́ aṣáájú méjìlá sọ́tọ̀, pẹ̀lú Ṣérébáyà, Hásábáyà àti mẹ́wàá lára àwọn arákùnrin wọn,

25. Mo sì fi òṣùwọ̀n wọn ọrẹ fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò tí ọba àti àwọn ìgbìmọ̀, awọn ìjòyè àti gbogbo ọmọ Ísírẹ́lì tí ó wà níbẹ̀ gbe fi sílẹ̀ fún ilé Ọlọ́run wa.

26. Mo fi òsùwọ̀n wọn ẹgbẹ̀talẹ̀láàdọ́ta (650) talẹ́ńtì sílifà, àti ohun èlò fàdákà tí ó wọn ọgọ́rùn ún talẹ́ńtì, talẹ́ńtì wúrà

Ka pipe ipin Ẹ́sírà 8