Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sírà 6:1-7 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà ni ọba Dáríúsì pàṣẹ, wọ́n sì wá inú ilé ìfí-nǹkan-pamọ́-sí ní ilé ìṣúra ní Bábílónì.

2. A rí ìwé kíká kan ní Ékíbátanà ibi kíkó ìwé sí ní ilé olódí agbégbé Médíà, wọ̀nyí ni ohun tí a kọ sínú rẹ̀:Ìwé ìrántí:

3. Ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba ọba Ṣáírúsì, ọba pa àṣẹ kan nípa tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run ní Jérúsálẹ́mù:Jẹ́ kí a tún tẹ́ḿpìlì ibi tí a ti ń rú onírúurú ẹbọ kọ́, kí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ ní gíga àti àádọ́rùn-ún (90) ẹsẹ̀ bàtà ní fífẹ̀,

4. pẹ̀lú ìpele òkúta ńlá ńlá mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti ìpele pákó kan, kí a san owó rẹ̀ láti inú ilé ìṣúra ọba.

5. Sì jẹ́ kí wúrà àti àwọn ohun èlò fàdákà ti ilé Ọlọ́run, tí Nebukadinésárì kó láti ilé Olúwa ní Jérúsálẹ́mù tí ó sì kó lọ sí Bábílónì, di dídá padà sí àyè wọn nínú tẹ́ḿpìlì ní Jérúsálẹ́mù; kí a kó wọn sí inú ilé Ọlọ́run.

6. Nítorí náà, kí ìwọ, Táténíà Baálẹ̀ agbègbè Yúfúrátè àti Ṣétarì-Bóṣénáì àti àwọn ẹlẹ́gbẹ́ yín, àwọn ìjòyè ti agbègbè náà, kúrò níbẹ̀.

7. Ẹ fi iṣẹ́ ilé Ọlọ́run yìí lọ́rùn sílẹ̀ láì díi lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ kí Baálẹ̀ àwọn Júù àti àwọn àgbààgbà Júù tún ilé Ọlọ́run yín kọ́ sí ipò rẹ̀.

Ka pipe ipin Ẹ́sírà 6