Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sírà 4:1-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí àwọn ọ̀ta Júdà àti Bẹ́ńjámínì gbọ́ wí pé àwọn ìgbèkùn tí ó padà dé ń kọ́ tẹ́ḿpìlì fún Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì,

2. wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Ṣérúbábélì àti sí ọ̀dọ̀ àwọn olórí àwọn ìdílé, wọ́n sì wí pé, “Jẹ́ kí a bá a yín kọ́ nítorí pé, bí i ti yín, a ń wá Ọlọ́run yín, a sì ti ń rúbọ sí i láti ìgbà Ésáríhádónì ọba Ásíríà, tí ó mú wa wá síbi yìí.”

3. Ṣùgbọ́n Ṣerubábélì, Jéṣúà àti ìyókù àwọn olórí àwọn ìdílé Ísírẹ́lì dáhùn pé, “Ẹ kò ní ipa pẹ̀lú wa ní kíkọ́ ilé fún Ọlọ́run wa. Àwa nìkan yóò kọ́ ọ fún Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, bí Sáírúsì, ọba Páṣíà, ti pàṣẹ fún wa.”

4. Nígbà náà ni àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà mú ọwọ́ àwọn ènìyàn Júdà rọ, wọ́n sì dẹ́rù bá wọ́n ní ti kíkọ́ ilé náà.

5. Wọ́n gba àwọn olùdámọ̀ràn láti ṣiṣẹ́ lòdì sí wọn àti láti sọ ète wọn di asán ní gbogbo àsìkò ìjọba Sáírúsì ọba Páṣíà àti títí dé ìgbà ìjọba Dáríúsì ọba Páṣíà.

6. Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Ṣérísésì wọ̀n fi ẹ̀sùn kan àwọn ènìyàn Júdà àti Jérúsálẹ́mù.

7. Àti ní àkókò ìjọba Aritaṣéṣéṣì ọba Páṣíà, Bíṣílámì, Mítírédátì, Tábélì àti àwọn ẹlẹ́gbẹ̀ rẹ̀ yóòkù kọ̀wé sí Aritaṣéṣéṣì. A kọ ìwé náà ní ìlànà ìkọ̀wé Árámáíkì èdè Árámáíkì sì ní a fi kọ ọ́.

8. Réhúmì balógun àti Ṣímíṣáì akọ̀wé jùmọ̀ kọ́ ìwé láti dojúkọ Jérúsálẹ́mù sí Aritaṣéṣéṣì ọba báyìí:

9. Réhúmì balógun àti Ṣímíṣáì akọ̀wé, pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tó kù—àwọn adájọ́ àti àwọn ìjòyè lórí àwọn ènìyàn láti Tírípólísì, Pásíà, Érékì àti Bábílónì, àwọn ará Élámì ti Súsà,

10. pẹ̀lú àwọn ènìyàn mìíràn tí ẹni ọlá àti ẹni ọ̀wọ̀ Áṣúríbánípálì lé jáde tí ó sì tẹ̀ wọ́n dó sí ìlú Samáríà àti níbòmíràn ní agbègbè e Yúfúrátè.

11. (Èyí ni ẹ̀dà ìwé tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí i.)Sí ọba Aritaṣéṣéṣì,Lati ọ̀dọ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àwọn ọkùnrin agbègbè Yúfúrátè:

12. Ọba gbọdọ̀ mọ̀ pé àwọn ará Júù tí ó gòkè wá sọ́dọ̀ wa láti ọ̀dọ̀ rẹ̀ ti lọ sí Jérúsálẹ́mù wọ́n sì ń tún ìlú búburú àti ìlú ọlọ̀tẹ̀ ẹ nì kọ́. Wọ́n ń tún àwọn ògiri náà kọ́, wọ́n sì ń tún àwọn ìpìlẹ̀ náà ṣe.

13. Ṣíwájú síi, ọba gbọdọ̀ mọ̀ pé tí a bá kọ́ ìlú yìí àti tí a sì tún àwọn ògiri rẹ̀ mọ, kò sí owó orí, owó òde tàbí owó ibodè tí a ó san, owó tí ó sì ń wọlé fún ọba yóò sì dínkù.

14. Nísinsìn yìí níwọ̀n ìgbà tí a ní ojúṣe sí ààfin ọba, kò sì bójúmu fún wa láti rí ìtàbùkù ọba, àwa ń rán iṣẹ́ yìí láti sọ fún ọba,

15. kí a bá a lè ṣe ìwádìí ní inú ìwé ìrántí àwọn àṣíwájú rẹ̀. Nínú ìwé ìrántí wọn yìí, ìwọ yóò ríi wí pé, ìlú yìí jẹ́ ìlú aṣọ̀tẹ̀, oní wàhálà sí àwọn ọba àti àwọn ìgbèríko, ibi ìṣọ̀tẹ̀ láti ìgbà àtijọ́. Ìdí ni èyí tí a ṣe pa ìlú yìí run.

16. A fi dá ọba lójú wí pé tí a bá tún ìlú kọ́ àti ti àwọn ògiri rẹ̀ si di mímọ padà, kì yóò sì ohun ti yóò kù ọ́ kù ní agbégbé Yúfúrátè.

Ka pipe ipin Ẹ́sírà 4