Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sírà 3:4-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Nígbà náà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ, wọ́n ṣe àpèjọ àgọ́ ìpàdé pẹ̀lú iye ọrẹ sísun tí a fi lélẹ̀ fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.

5. Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣe ìrúbọ ẹbọ sísun àti-gbà-dé-gbà, ẹbọ oṣù tuntun àti gbogbo àwọn ẹbọ fún gbogbo àpèjẹ tí a yà sọ́tọ̀ fún Olúwa, àti àwọn tí a mú wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àtinúwá fún Olúwa.

6. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù keje, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní rú ọrẹ sísun sí Olúwa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò ì tí ì fi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa lélẹ̀.

7. Nígbà náà ni wọ́n fún àwọn ọ̀mọ̀lé àti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà ní owó, wọ́n sì tún fi oúnjẹ, ohun mímu àti òróró fún àwọn ará Ṣídónì àti Tírè, kí wọ́n ba à le è kó igi Sídà gba ti orí omi òkun láti Lébánónì wá sí Jópà, gẹ́gẹ́ bí Sáírúsì ọba Páṣíà ti pàṣẹ.

8. Ní oṣù kejì ọdún kejì lẹ́yìn tí wọ́n ti padà dé sí ilé Olúwa ní Jérúsálẹ́mù, Ṣérúbábélì ọmọ Ṣéálítíélì, Jéṣúà ọmọ Jósádákì àti àwọn arákùnrin yóòkù (àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì àti gbogbo àwọn tí ó ti ìgbèkùn dé sí Jérúsálẹ́mù) bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà. Wọ́n sì yan àwọn ọmọ Léfì tí ó tó ọmọ ogun ọdún sókè láti máa bojútó kíkọ́ ilé Olúwa.

9. Jéṣúà àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn arákùnrin rẹ̀ àti Kádímíélì àti àwọn ọmọ rẹ̀ (àwọn ìránṣẹ́ Hódáfíà) àti àwọn ọmọ Hénádádì àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn arákùnrin wọn—gbogbo ará Léfì—parapọ̀ láti bojútó àwọn òṣìṣẹ́ náà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ lórí í kíkọ́ ilé Ọlọ́run.

10. Nígbà tí àwọn ọ̀mọ̀lé gbé ìpìlẹ̀ ilé Olúwa kalẹ̀, àwọn àlùfáà nínú aṣọ iṣẹ́ àlùfáà wọn pẹ̀lú fèrè, àti àwọn ará Léfì (Àwọn ọmọ Ásáfù) pẹ̀lú Kíńbálì, dúró ní ipò wọn láti yin Olúwa, bí Dáfídì ọba Ísírẹ́lì ti fi lélẹ̀.

11. Pẹ̀lú ìyìn àti ọpẹ́ ni wọ́n kọrin sí Olúwa:“Ó dára;ìfẹ́ rẹ̀ sí Ísírẹ́lì dúró títí láé.”Gbogbo àwọn ènìyàn sì fi ohùn ariwo ńlá yin Olúwa, nítorí tí a ti fi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa lélẹ̀.

12. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ lára àwọn àgbà àlùfáà àti àwọn ará Léfì àti àwọn olórí ìdílé, tí ó ti rí tẹ́ḿpìlì Olúwa ti tẹ́lẹ̀, wọ́n sunkún kíkorò nígbà tí wọ́n rí ìpìlẹ̀ tẹ́ḿpìlì Olúwa yìí tí wọ́n fi lélẹ̀, nígbà tí ọ̀pọ̀ kígbe fún ayọ̀.

13. Kò sí ẹni tí ó le mọ́ ìyàtọ̀ láàárin igbe ayọ̀ àti ẹkún, nítorí tí ariwo àwọn ènìyàn náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́. Wọ́n sì gbọ́ igbe náà ní ọ̀nà jínjìn réré.

Ka pipe ipin Ẹ́sírà 3