Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sírà 3:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà tí ó di oṣù keje tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ti wà nínú àwọn ìlú wọn, àwọn ènìyàn péjọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹnìkan ní Jérúsálẹ́mù.

2. Nígbà náà ni Jéṣúà ọmọ Jósádákì àti àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ ẹ rẹ̀ Ṣérúbábélì ọmọ Ṣéálítíélì àti àwọn ènìyàn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí ní kọ́ pẹpẹ Ọlọ́run Ísírẹ́lì láti rú ẹbọ sísun níbẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ìlànà tí a ti kọ sínú ìwé òfin Mósè ènìyàn Ọlọ́run

3. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ẹ̀rù àwọn ènìyàn tí ó yí wọn ká ń bà wọ́n ṣíbẹ̀, wọ́n kọ́ pẹpẹ sórí ìpìlẹ̀ rẹ̀, wọ́n sì rú ọrẹ sísun lórí rẹ̀ sí Olúwa, ọrẹ àárọ̀ àti ìrọ̀lẹ́.

4. Nígbà náà ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí a kọ, wọ́n ṣe àpèjọ àgọ́ ìpàdé pẹ̀lú iye ọrẹ sísun tí a fi lélẹ̀ fún ọjọ́ kọ̀ọ̀kan.

5. Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣe ìrúbọ ẹbọ sísun àti-gbà-dé-gbà, ẹbọ oṣù tuntun àti gbogbo àwọn ẹbọ fún gbogbo àpèjẹ tí a yà sọ́tọ̀ fún Olúwa, àti àwọn tí a mú wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àtinúwá fún Olúwa.

6. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù keje, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní rú ọrẹ sísun sí Olúwa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò ì tí ì fi ìpìlẹ̀ ilé Olúwa lélẹ̀.

7. Nígbà náà ni wọ́n fún àwọn ọ̀mọ̀lé àti àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà ní owó, wọ́n sì tún fi oúnjẹ, ohun mímu àti òróró fún àwọn ará Ṣídónì àti Tírè, kí wọ́n ba à le è kó igi Sídà gba ti orí omi òkun láti Lébánónì wá sí Jópà, gẹ́gẹ́ bí Sáírúsì ọba Páṣíà ti pàṣẹ.

8. Ní oṣù kejì ọdún kejì lẹ́yìn tí wọ́n ti padà dé sí ilé Olúwa ní Jérúsálẹ́mù, Ṣérúbábélì ọmọ Ṣéálítíélì, Jéṣúà ọmọ Jósádákì àti àwọn arákùnrin yóòkù (àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì àti gbogbo àwọn tí ó ti ìgbèkùn dé sí Jérúsálẹ́mù) bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ náà. Wọ́n sì yan àwọn ọmọ Léfì tí ó tó ọmọ ogun ọdún sókè láti máa bojútó kíkọ́ ilé Olúwa.

Ka pipe ipin Ẹ́sírà 3