Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹ́sírà 10:6-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Nígbà náà ni Ẹ́sírà padà sẹ́yìn kúrò níwájú ilé Ọlọ́run, ó sì lọ sí iyàrá Jéhóhánánì ọmọ Élíásíbù. Nígbà tí ó wà níbẹ̀, kò jẹ oúnjẹ bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu omi, nítorí ó sì ń káàánú fún àìsòótọ́ àwọn ìgbèkùn.

7. Ìkèdè kan jáde lọ jákèjádò Júdà àti Jérúsálẹ́mù fún gbogbo àwọn ìgbèkùn láti péjọ sí Jérúsálẹ́mù.

8. Ẹnikẹ́ni tí ó ba kọ̀ láti jáde wá láàrin ọjọ́ mẹ́ta yóò pàdánù ohun ìní rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìpinnu àwọn ìjòyè àti àwọn àgbààgbà, àti pé a ó lé òun fúnraaarẹ̀ jáde kúrò láàrin ìpéjọpọ̀ àwọn ìgbèkùn.

9. Láàrin ọjọ́ mẹ́ta náà, gbogbo àwọn ọkùnrin Júdà àti Bẹ́ńjámínì tí péjọ sí Jérúsálẹ́mù. Ní ogúnjọ́ oṣù kẹ́sàn án, gbogbo àwọn ènìyàn jókòó sí ìta gbangba iwájú ilé Ọlọ́run, wọ́n wà nínú ìbànújẹ́ ńlá nítorí ọ̀ran yìí, àti nítorí òjò púpọ̀ tó tì rọ̀.

10. Nígbà náà ni àlùfáà Ẹ́sírà dìde, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ti ṣe àìsòótọ́, ẹ ti fẹ́ obìnrin àjèjì, ẹ ti dá kún ẹ̀bi Ísírẹ́lì.

11. Nísinsìnyìí, ẹ jẹ́wọ́ níwájú Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba yín, kí ẹ sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kúrò láàrin àwọn ènìyàn tí ó yí i yín ká àti láàrin àwọn ìyàwó àjèjì yín.”

12. Àpéjọpọ̀ ènìyàn náà sì dáhùn lóhùn rara pé: ohun tí ó sọ dára! A gbọdọ̀ ṣe bí o ti wí.

13. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ ni ó wà ni ibi yìí ṣíbẹ̀ àkókò òjò ni; àwa kò sì lè dúró níta. Yàtọ̀ sí èyí, a kò le è yanjú ọ̀rọ̀ yìí láàrin ọjọ́ kan tàbí ọjọ́ méjì, nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa pọ̀ jọjọ lórí awọn nǹkan wọ̀nyí.

14. Jẹ́ kí àwọn ìjòyè wa ṣojú fún gbogbo ìjọ ènìyàn, lẹ́yìn náà, jẹ́ kí ẹnìkọ̀ọ̀kan nínú àwọn ìlú wa tí ó ti fẹ obìnrin àjèjì wá ní àsìkò tí a yàn, pẹ̀lú àwọn àgbààgbà àti àwọn onídàájọ́ ìlú kọ̀ọ̀kan, títí ìbínú gíga Ọlọ́run wa lórí ọ̀rọ̀ yìí yóò fi kúrò ní orí wa.

15. Jónátanì ọmọ Ásáhélì àti Jáhéséáyà ọmọ Jíkífà nìkan pẹ̀lú àtìlẹyìn Mésísúlámù àti Ṣíábétaì ará Léfì, ni wọ́n tako àbá yìí.

16. Nígbà náà ni àwọn ìgbèkùn ṣe gẹ́gẹ́ bí wọ́n se fi ẹnu kò sí. Àlùfáà Ẹ́sírà yan àwọn ọkùnrin tí wọ́n jẹ́ olórí àwọn ìdílé, ẹnìkọ̀ọ̀kan láti ìdílé kọ̀ọ̀kan, gbogbo wọn ni a sì mọ̀ pẹ̀lú orúkọ wọn. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kẹwàá, wọ́n jòkóó láti ṣe àyẹ̀wò àwọn ẹjọ́ náà,

Ka pipe ipin Ẹ́sírà 10