Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkún Jeremáyà 4:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Báwo ni wúrà ṣe sọ ògo dídán rẹ̀ nù,wúrà dídára di àìdán!Òkúta ibi mímọ́ wá túkásí oríta gbogbo òpópó.

2. Báwo ni àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin Síónì tí ó ṣe iyebíye,tí wọ́n wọn iye wúrà ṣewá dàbí ìkòkò amọ̀ lásániṣẹ́ ọwọ́ amọ̀kòkò!

3. Àwọn ọ̀wàwà pèsè ọmú wọnfún ìtọ́jú àwọn ọmọ wọn,ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn mi wá láì lọ́kànbí ògòǹgò ní aṣálẹ̀.

4. Nítorí òùngbẹ, ahọ́n àwọn ọmọ ọwọ́lẹ̀ mọ́ òkè ẹnu wọn;àwọn ọmọdé bẹ̀bẹ̀ fún oúnjẹṢùgbọ́n kòsí ẹni tí ó fi fún wọn.

5. Àwọn tí ó ń jẹ ohun dáradáradi òtòsì ní òpópó.Àwọn tí a fi aṣọ dáradára wọ̀ni wọ́n sùn ní orí òkítì eérú.

Ka pipe ipin Ẹkún Jeremáyà 4