Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkún Jeremáyà 3:6-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Ó mú mi gbé nínú òkùnkùnbí ti àwọn tó ti kú fún ìgbà pípẹ́.

7. Ó ti tì mí mọ́lé nítorí náà n kò le è sálọ;ó ti fi ẹ̀wọ̀n mú mi mọ́lẹ̀

8. Pàápàá nígbà tí mo ké fún ìrànlọ́wọ́,ó kọ àdúrà mi.

9. Ó fi búlọ́kù òkúta dí ọ̀nà mi;ó sì mú ọ̀nà mi wọ́

10. Bí i béárì tí ó dùbúlẹ̀,bí i kìnnìún tí ó sá pamọ́.

11. Ó wọ́ mi kúrò ní ọ̀nà, ó tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ó fi mi sílẹ̀ láì sí ìrànlọ́wọ́.

12. Ó fa ọfà rẹ̀ yọó sì fi mí sohun ìtafàsí.

13. Ó fa ọkàn mí yapẹ̀lú ọfà nínú àkọ̀ rẹ̀.

14. Mo di ẹni yẹ̀yẹ́ láàrin àwọn ènìyàn mi;wọn yẹ̀yẹ́ mi pẹ̀lú orin ní gbogbo ọjọ́.

15. Ó ti kún mi pẹ̀lú ewé kíkoròàti ìdààmú bí omi.

16. Ó ti fi òkúta kán ẹyín mi;ó ti tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ nínú eruku.

17. Mo ti jìnnà sí àlàáfíà;Mo ti gbàgbé ohun tí àṣeyege ń ṣe.

18. Nítorí náà mo wí pé, “Ògo mi ti lọàti ìrètí mi nínú Olúwa.”

19. Mo ṣe ìrántí ìpọ́njú àti ìdààmú mi,ìkorò àti ìbànújẹ́.

20. Mo ṣèrántí wọn,ọkàn mi sì gbọgbẹ́ nínú mi.

Ka pipe ipin Ẹkún Jeremáyà 3