Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkún Jeremáyà 3:52-59 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

52. Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìídẹ mí bí ẹyẹ.

53. Wọ́n gbìyànjú láti mú òpin dé bá ayé mi nínú ihòwọ́n sì ju òkúta lù mí.

54. Orí mi kún fún omi,mo sì rò pé ìgbẹ̀yìn dé.

55. Mo pe orúkọ rẹ, Olúwa,láti ọ̀gbun ìsàlẹ̀ ihò.

56. Ìwọ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi: “Má ṣe di etí rẹsí igbe ẹ̀bẹ̀ mi fún ìtura.”

57. O wá tòsí nígbà tí mo ké pè ọ́,o sì wí pé, “Má se bẹ̀rù.”

58. Olúwa, ìwọ gba ẹjọ́ mi rò,o ra ẹ̀mí mi padà.

59. O ti rí i, Olúwa, búburú tí a ṣe sí miGbé ẹjọ́ mi ró!

Ka pipe ipin Ẹkún Jeremáyà 3