Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkún Jeremáyà 3:49-66 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

49. Ojú mi kò dá fún omijé,láì sinmi,

50. títí ìgbà tí Olúwa síjú wolẹ̀láti òkè ọ̀run tí yóò sì rí i.

51. Ohun tí mo rí mú ìbẹ̀rù wá ọkàn minítorí gbogbo àwọn obìnrin ìlú mi.

52. Àwọn tí ó jẹ́ ọ̀tá mi láìnídìídẹ mí bí ẹyẹ.

53. Wọ́n gbìyànjú láti mú òpin dé bá ayé mi nínú ihòwọ́n sì ju òkúta lù mí.

54. Orí mi kún fún omi,mo sì rò pé ìgbẹ̀yìn dé.

55. Mo pe orúkọ rẹ, Olúwa,láti ọ̀gbun ìsàlẹ̀ ihò.

56. Ìwọ gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi: “Má ṣe di etí rẹsí igbe ẹ̀bẹ̀ mi fún ìtura.”

57. O wá tòsí nígbà tí mo ké pè ọ́,o sì wí pé, “Má se bẹ̀rù.”

58. Olúwa, ìwọ gba ẹjọ́ mi rò,o ra ẹ̀mí mi padà.

59. O ti rí i, Olúwa, búburú tí a ṣe sí miGbé ẹjọ́ mi ró!

60. Ìwọ ti rí ọ̀gbun ẹ̀san wọn,gbogbo ìmọ̀ wọn sí mi.

61. Olúwa ìwọ ti gbọ́ ẹ̀gàn wọnàti ìmọ̀ búburú wọn sí mi—

62. Ohun tí àwọn ọ̀tá mi ń sọsí mi ní gbogbo ọjọ́.

63. Wò wọ́n! Ní jíjòkòó tàbí ní dídìde,wọ́n ń ṣẹlẹ́yà mi nínú orin wọn.

64. Olúwa san wọ́n lẹ́san ohun tí ó tọ́ sí wọnfún ohun tí ọwọ́ wọn ti ṣe.

65. Fi ìbòjú bò wọ́n ní ọkàn,kí o sì fi wọ́n ré.

66. Ni wọ́n lára kí o sì pa wọ́n run pẹ̀lú ìbínú,lábẹ́ ọ̀run Olúwa.

Ka pipe ipin Ẹkún Jeremáyà 3