Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkún Jeremáyà 3:33-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

33. Nítorí kò mọ̀ọ́mọ̀ mú ìpọ́njú wátàbí ìrora wá fún ọmọ ènìyàn.

34. Kí ó tẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n ní ilẹ̀ náà.

35. Láti ṣẹ́ ọmọ ènìyàn fún ẹ̀tọ́ rẹ̀níwájú ẹni ńlá.

36. Láti yí ìdájọ́ ènìyàn po,Ǹjẹ́ Olúwa kò rí ohun bẹ́ẹ̀.

37. Ta ni yóò sọ̀rọ̀ tí yóò rí bẹ́ẹ̀tí Olúwa kò bá fàṣẹ sí i.

38. Ǹjẹ́ kì í ṣe láti ẹnu ẹni ńláni dídára àti búburú tí ń wá?

39. Kí ló dé tí ẹ̀dá alàyè ṣe ń kùnnígbà tí ó bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

40. Ẹ jẹ́ kí a yẹ ọ̀nà wa kí a sì dán an wò,kí a sì tọ Olúwa lọ.

Ka pipe ipin Ẹkún Jeremáyà 3