Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkún Jeremáyà 3:22-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Nítorí ìfẹ́ Olúwa tí ó lágbára ni àwa kò fi ṣègbé,nítorí àánú rẹ kì í kùnà.

23. Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àárọ̀;títóbi ni òdodo rẹ̀.

24. Mo wí fún ara mi, ìpín mi ni Olúwa;nítorí náà èmi yóò dúró dè ọ́

25. Dídára ni Olúwa fún àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ̀,sí àwọn tí ó ń wá a.

26. Ó dára kí a ní ṣùúrùfún ìgbàlà Olúwa.

27. Ó dára fún ènìyàn láti gbé àjàgànígbà tí ó wà ní èwe.

28. Jẹ́ kí ó jókòó ní ìdákẹ́jẹ́,nítorí Olúwa ti fi fún un.

29. Jẹ́ kí ó bò ojú rẹ̀ sínú eruku—ìrètí sì lè wà.

30. Jẹ́ kí ó fi ẹ̀rẹ̀kẹ́ fún àwọn tí yóò gbá a,sì jẹ́ kí ó wà ní ìdójútì.

31. Ènìyàn kò di ìtanùlọ́dọ̀ Olúwa títí láé.

32. Lóòtọ́ ó mú ìbànújẹ́ wá, yóò fi àánú hàn,nítorí náà títóbi ni ìfẹ́ rẹ̀.

33. Nítorí kò mọ̀ọ́mọ̀ mú ìpọ́njú wátàbí ìrora wá fún ọmọ ènìyàn.

34. Kí ó tẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n ní ilẹ̀ náà.

35. Láti ṣẹ́ ọmọ ènìyàn fún ẹ̀tọ́ rẹ̀níwájú ẹni ńlá.

36. Láti yí ìdájọ́ ènìyàn po,Ǹjẹ́ Olúwa kò rí ohun bẹ́ẹ̀.

37. Ta ni yóò sọ̀rọ̀ tí yóò rí bẹ́ẹ̀tí Olúwa kò bá fàṣẹ sí i.

38. Ǹjẹ́ kì í ṣe láti ẹnu ẹni ńláni dídára àti búburú tí ń wá?

Ka pipe ipin Ẹkún Jeremáyà 3