Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkún Jeremáyà 3:22-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

22. Nítorí ìfẹ́ Olúwa tí ó lágbára ni àwa kò fi ṣègbé,nítorí àánú rẹ kì í kùnà.

23. Wọ́n jẹ́ ọ̀tún ní àárọ̀;títóbi ni òdodo rẹ̀.

24. Mo wí fún ara mi, ìpín mi ni Olúwa;nítorí náà èmi yóò dúró dè ọ́

25. Dídára ni Olúwa fún àwọn tí ó ní ìrètí nínú rẹ̀,sí àwọn tí ó ń wá a.

26. Ó dára kí a ní ṣùúrùfún ìgbàlà Olúwa.

27. Ó dára fún ènìyàn láti gbé àjàgànígbà tí ó wà ní èwe.

28. Jẹ́ kí ó jókòó ní ìdákẹ́jẹ́,nítorí Olúwa ti fi fún un.

29. Jẹ́ kí ó bò ojú rẹ̀ sínú eruku—ìrètí sì lè wà.

30. Jẹ́ kí ó fi ẹ̀rẹ̀kẹ́ fún àwọn tí yóò gbá a,sì jẹ́ kí ó wà ní ìdójútì.

31. Ènìyàn kò di ìtanùlọ́dọ̀ Olúwa títí láé.

32. Lóòtọ́ ó mú ìbànújẹ́ wá, yóò fi àánú hàn,nítorí náà títóbi ni ìfẹ́ rẹ̀.

Ka pipe ipin Ẹkún Jeremáyà 3