Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkún Jeremáyà 3:15-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ó ti kún mi pẹ̀lú ewé kíkoròàti ìdààmú bí omi.

16. Ó ti fi òkúta kán ẹyín mi;ó ti tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ nínú eruku.

17. Mo ti jìnnà sí àlàáfíà;Mo ti gbàgbé ohun tí àṣeyege ń ṣe.

18. Nítorí náà mo wí pé, “Ògo mi ti lọàti ìrètí mi nínú Olúwa.”

19. Mo ṣe ìrántí ìpọ́njú àti ìdààmú mi,ìkorò àti ìbànújẹ́.

20. Mo ṣèrántí wọn,ọkàn mi sì gbọgbẹ́ nínú mi.

21. Síbẹ̀, èyí ni mo ní ní ọkànàti nítorí náà ní mo nírètí.

Ka pipe ipin Ẹkún Jeremáyà 3