Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹkún Jeremáyà 3:12-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ó fa ọfà rẹ̀ yọó sì fi mí sohun ìtafàsí.

13. Ó fa ọkàn mí yapẹ̀lú ọfà nínú àkọ̀ rẹ̀.

14. Mo di ẹni yẹ̀yẹ́ láàrin àwọn ènìyàn mi;wọn yẹ̀yẹ́ mi pẹ̀lú orin ní gbogbo ọjọ́.

15. Ó ti kún mi pẹ̀lú ewé kíkoròàti ìdààmú bí omi.

16. Ó ti fi òkúta kán ẹyín mi;ó ti tẹ̀ mí mọ́lẹ̀ nínú eruku.

17. Mo ti jìnnà sí àlàáfíà;Mo ti gbàgbé ohun tí àṣeyege ń ṣe.

18. Nítorí náà mo wí pé, “Ògo mi ti lọàti ìrètí mi nínú Olúwa.”

19. Mo ṣe ìrántí ìpọ́njú àti ìdààmú mi,ìkorò àti ìbànújẹ́.

Ka pipe ipin Ẹkún Jeremáyà 3