1. Èmi ni ọkùnrin tí ó rí ìpọ́njúpẹ̀lú ọ̀pá ìbínú.
2. Ó ti lémi jáde ó sì mú mi rìnnínú òkùnkùn ju ti ìmọ́lẹ̀;
3. Nítòótọ́, ó ti yí ọwọ́ padà sí misíwájú àti síwájú sí i ní gbogbo ọjọ́.
4. Ó jẹ́ kí àwọ̀ mi àti ẹran ara mi gbóó sì tún ṣẹ́ egungun mi.
5. Ó ti fi mí sí ìgbèkùn ó sì ti yí mi kápẹ̀lú ìkorò àti làálàá.
6. Ó mú mi gbé nínú òkùnkùnbí ti àwọn tó ti kú fún ìgbà pípẹ́.
7. Ó ti tì mí mọ́lé nítorí náà n kò le è sálọ;ó ti fi ẹ̀wọ̀n mú mi mọ́lẹ̀
8. Pàápàá nígbà tí mo ké fún ìrànlọ́wọ́,ó kọ àdúrà mi.
9. Ó fi búlọ́kù òkúta dí ọ̀nà mi;ó sì mú ọ̀nà mi wọ́