Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 9:26-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Ilẹ̀ Gósénì ni ibi ti àwọn Ísírẹ́lì wà nikan ni òjò yìnyín náà kò rọ̀ dé.

27. Nígbà náà ni Fáráò pe Mósè àti Árónì sì ọ̀dọ́ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Èmi ti ṣẹ̀ ní àkókò yìí; Olúwa jẹ́ olódodo ṣùgbọ́n èmi àti àwọn ènìyàn mi ni aláìsòdodo.

28. Èyí ti òjò yìnyín àti àrá rọ̀ yìí tó gẹ́ẹ́, gbàdúrà sí Olúwa kí ó dáwọ́ rẹ̀ dúró. Èmi yóò jẹ́ kí ẹ lọ, n kò tún ni dá a yín dúró mọ́.”

29. Mósè dá a lóhùn pé, “Bí mo bá ti jáde kúró ní àárin ilú, èmi yóò gbé ọwọ́ mi sókè sí Olúwa, sísàn àrá yóò dáwọ́ dúró, yìnyín kò sì ni rọ̀ mọ́, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé Olúwa ni ó ni ilẹ̀.

30. Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ pé ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ ìwọ àti àwọn ìjòyè rẹ kò bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run.”

31. (Òwú àti ọkà báálì sí bàjẹ́ ni ìwọ̀n ìgbà ti wọn so ṣùgbọ́n ti ọkà-báálì kò lajú ti òwú kò sì là.

32. Onírúurú ọkà-wíìtì (jéró àti sípélítì) kò bàjẹ́, èṣo wọn padà gbó nítorí wọ́n máa ń pẹ so.)

33. Nígbà náà ni Mósè kúrò ni iwájú Fáráò, ó kúrò ni àárin ìgboro kọjá lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú, ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí Olúwa, sísán àrá àti òjò yìnyín ti ń rọ̀ sì dáwọ́ dúró, òjò kò sì rọ̀ sí orí ilẹ̀ mọ́.

34. Nígbà tí Fáráò rí i pé òjò àti yìnyín àti àrá ti ń sán ti dáwọ́ dúró, ó tún ṣè ní ẹ̀ẹ̀kan sí i. Ọkan Fáráò àti àwọn ìjòyè rẹ̀ yigbì.

35. Ọkàn Fáráò sì yigbì, kò sì jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ó lọ, bí Olúwa ti sọ láti ẹnu Mósè.

Ka pipe ipin Ékísódù 9