Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 9:26-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

26. Ilẹ̀ Gósénì ni ibi ti àwọn Ísírẹ́lì wà nikan ni òjò yìnyín náà kò rọ̀ dé.

27. Nígbà náà ni Fáráò pe Mósè àti Árónì sì ọ̀dọ́ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Èmi ti ṣẹ̀ ní àkókò yìí; Olúwa jẹ́ olódodo ṣùgbọ́n èmi àti àwọn ènìyàn mi ni aláìsòdodo.

28. Èyí ti òjò yìnyín àti àrá rọ̀ yìí tó gẹ́ẹ́, gbàdúrà sí Olúwa kí ó dáwọ́ rẹ̀ dúró. Èmi yóò jẹ́ kí ẹ lọ, n kò tún ni dá a yín dúró mọ́.”

29. Mósè dá a lóhùn pé, “Bí mo bá ti jáde kúró ní àárin ilú, èmi yóò gbé ọwọ́ mi sókè sí Olúwa, sísàn àrá yóò dáwọ́ dúró, yìnyín kò sì ni rọ̀ mọ́, kí ìwọ kí ó lè mọ̀ pé Olúwa ni ó ni ilẹ̀.

30. Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ pé ṣíbẹ̀ṣíbẹ̀ ìwọ àti àwọn ìjòyè rẹ kò bẹ̀rù Olúwa Ọlọ́run.”

Ka pipe ipin Ékísódù 9