Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 7:1-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè pé, “Wò ó, èmi ti ṣe ọ bí Ọlọ́run fún Fáráò, Árónì arákùnrin rẹ ni yóò jẹ́ wòlíì (agbẹnusọ) rẹ.

2. Ìwọ yóò sì sọ ohun gbogbo tí èmi ti pàṣẹ fún ọ, Árónì arákùnrin rẹ yóò sí sọ fún Fáráò kí ó jẹ́ kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò ni ilẹ̀ rẹ̀.

3. Ṣùgbọ́n èmi yóò ṣé Fáráò lọ́kàn le. Bí mo tilẹ̀ ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ àmì àti ìyanu ni Éjíbítì,

4. ṣíbẹ̀ òun kì yóò fi etí sí ọ. Nígbà náà ni èmi yóò gbé ọwọ́ mi lé Éjíbítì, pẹ̀lú agbára ìdájọ́ ńlá mi ni èmi yóò mú àwọn ènìyàn mi Ísírẹ́lì jáde ní ọ̀wọ̀ọ̀wọ́.

5. Àwọn ará Éjíbítì yóò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa ní ìgbà tí mo bá na ọwọ́ mi jáde lé Éjíbítì, tí mo sì mú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò níbẹ̀.”

6. Mósè àti Árónì sì ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ́ fún wọn.

7. Mósè jẹ́ ọmọ ọgọ́rin ọdún (80) Árónì sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́talélọ́gọ́rin (83) ni ìgbà tí wọ́n bá Fáráò sọ̀rọ̀.

8. Olúwa sọ fún Mósè àti Árónì,

9. “Ní ìgbà tí Fáráò bá sọ fún un yín pé, ‘Ẹ ṣe iṣẹ́ ìyanu kan,’ sọ fún Árónì ní ìgbà náà pé, ‘Mú ọ̀pá rẹ kí ó sì sọ ọ́ sílẹ̀ níwájú Fáráò,’ yóò sì di ejò.”

10. Nígbà náà ni Mósè àti Árónì tọ Fáráò lọ, wọ́n sì ṣe bí Olúwa ti pàṣẹ fún wọn, Árónì ju ọ̀pá rẹ̀ sílẹ̀ ní ìwájú Fáráò àti àwọn ìjòyè rẹ̀, ọ̀pá náà sì di ejò.

11. Fáráò sì pe àwọn amòye, àwọn osó àti àwọn onídán ilẹ̀ Éjíbítì jọ, wọ́n sì fi idán wọn ṣe ohun tí Mósè àti Árónì ṣe.

Ka pipe ipin Ékísódù 7