Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 6:8-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Èmi yóò mú un yín wá ilẹ̀ náà ti èmi ti búra pẹ̀lú ìgbọ́wọ́sókè láti fi fún Ábúráhámù. Ísáákì àti Jákọ́bù. Èmi yóò fi fún un yín bí ohun ìní, èmi ni Olúwa.’ ”

9. Mósè sì sọ èyí fún àwọn ará Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n wọn kò fi etí sílẹ̀ sí Mósè nítorí ọkàn wọn tó rẹ̀wẹ̀sì àti nítorí ìgbékùn búburú bí ohun tí ó ti kọ́ sọ kó wọn sí ní oko ẹrú wọn.

10. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè.

11. “Lọ, sọ fún Fáráò ọba Éjíbítì pé kí ó jẹ́ kí àwọn ará Ísírẹ́lì lọ kúró ní orílẹ̀ èdè rẹ̀.”

12. Ṣùgbọ́n Mósè sọ fún Olúwa pé, “Nígbà ti àwọn ará Ísírẹ́lì tó jẹ́ ènìyàn mi kó fetí sí ọ̀rọ̀ mi, báwo ni Fáráò yóò se fetí sí ọ̀rọ̀ mi, nígbà ti mo jẹ́ akólòlò?”

13. Olúwa bá ìran Mósè àti Árònì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ará Ísírẹ́lì àti Fáráò ọba Íjibítì, ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọn kó àwọn Ísírẹ́lì jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì.

14. Wọ̀nyí ni olórí ìran wọn:Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àkọ́bí Ísírẹ́lì ni Hánókù, Pálù, Hésúrónì àti Kámì. Àwọn wọ̀nyí ni ìdílé Rúbẹ́nì.

15. Àwọn ọmọ Ṣímóní ní Jémúẹ́lì, Jámì, Óhádì, Jákínì, Ṣóhárì àti Ṣọ́ọ̀lù ọmọ obìnrin Kénánì. Àwọn wọ̀nyí ni ìran Símónì.

16. Ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn:Gésónì, Kóhábì àti Mérárì: Léfì lo ẹ̀tàndínlógóje (137) ọdún láyé.

17. Àwọn ọmọ Gésónì ni ìran wọn ni Líbínì àti Ṣímẹ́lì.

18. Àwọn ọmọ Kóhátì ni Ámírámù, Ísárì, Hébírónì àti Yúsíélì. Kóhátì lo ẹ̀tàléláádóje (133) ọdún láyé.

19. Àwọn ọmọ Mérárì ni Máhílì àti Músíhì.Ìwọ̀nyí ni ìran Léfì gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn.

20. Ámírámù sì fẹ́ Jókébédì arákùnrin baba rẹ̀ ní ìyàwó. Jókébédì sì bí Árónì àti Mósè fún un. Ámírámù lo ẹ̀tàdínlógóje (137) ọdún láyé.

21. Àwọn ọmọ Ísárì ni Kórà, Nẹ́fẹ́fì àti Ṣíkírì.

22. Àwọn ọmọ Yúṣíélì ni Míṣíháẹlì, Élíṣáfánì àti Ṣítíhírí.

23. Árónì fẹ́ Élíṣahẹ́ba ọmọbìnrin Ámínádábù tí í ṣe arábìnrin Náhísíhónì, ó sì bí Nádábù, Ábíhù, Élíásárì àti Ítamárì.

24. Àwọn ọmọ Kórà ni Ásírì, Élíkánà àti Ábíásáfù, ìwọ̀nyí ni ìran Kórà.

25. Élíásárì ọmọ Árónì fẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin Pútíẹ́lì ní ìyàwó, ó sì bí Fínéhásì fún un.Ìwọ̀nyí ni olórí àwọn Léfì ni ìdílé ìdílé.

26. Árónì àti Mósè yìí kan náà ni Olúwa sọ fún pé, “Ẹ kó àwọn ará Ísírẹ́lì jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì ní ìsọ̀rí ìsọ̀rí.”

Ka pipe ipin Ékísódù 6