Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 6:13-30 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Olúwa bá ìran Mósè àti Árònì sọ̀rọ̀ nípa àwọn ará Ísírẹ́lì àti Fáráò ọba Íjibítì, ó pàṣẹ fún wọn pé kí wọn kó àwọn Ísírẹ́lì jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì.

14. Wọ̀nyí ni olórí ìran wọn:Àwọn ọmọ Rúbẹ́nì àkọ́bí Ísírẹ́lì ni Hánókù, Pálù, Hésúrónì àti Kámì. Àwọn wọ̀nyí ni ìdílé Rúbẹ́nì.

15. Àwọn ọmọ Ṣímóní ní Jémúẹ́lì, Jámì, Óhádì, Jákínì, Ṣóhárì àti Ṣọ́ọ̀lù ọmọ obìnrin Kénánì. Àwọn wọ̀nyí ni ìran Símónì.

16. Ìwọ̀nyí ni orúkọ àwọn ọmọ Léfì gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn:Gésónì, Kóhábì àti Mérárì: Léfì lo ẹ̀tàndínlógóje (137) ọdún láyé.

17. Àwọn ọmọ Gésónì ni ìran wọn ni Líbínì àti Ṣímẹ́lì.

18. Àwọn ọmọ Kóhátì ni Ámírámù, Ísárì, Hébírónì àti Yúsíélì. Kóhátì lo ẹ̀tàléláádóje (133) ọdún láyé.

19. Àwọn ọmọ Mérárì ni Máhílì àti Músíhì.Ìwọ̀nyí ni ìran Léfì gẹ́gẹ́ bí àkọsílẹ̀ wọn.

20. Ámírámù sì fẹ́ Jókébédì arákùnrin baba rẹ̀ ní ìyàwó. Jókébédì sì bí Árónì àti Mósè fún un. Ámírámù lo ẹ̀tàdínlógóje (137) ọdún láyé.

21. Àwọn ọmọ Ísárì ni Kórà, Nẹ́fẹ́fì àti Ṣíkírì.

22. Àwọn ọmọ Yúṣíélì ni Míṣíháẹlì, Élíṣáfánì àti Ṣítíhírí.

23. Árónì fẹ́ Élíṣahẹ́ba ọmọbìnrin Ámínádábù tí í ṣe arábìnrin Náhísíhónì, ó sì bí Nádábù, Ábíhù, Élíásárì àti Ítamárì.

24. Àwọn ọmọ Kórà ni Ásírì, Élíkánà àti Ábíásáfù, ìwọ̀nyí ni ìran Kórà.

25. Élíásárì ọmọ Árónì fẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin Pútíẹ́lì ní ìyàwó, ó sì bí Fínéhásì fún un.Ìwọ̀nyí ni olórí àwọn Léfì ni ìdílé ìdílé.

26. Árónì àti Mósè yìí kan náà ni Olúwa sọ fún pé, “Ẹ kó àwọn ará Ísírẹ́lì jáde kúrò ni ilẹ̀ Éjíbítì ní ìsọ̀rí ìsọ̀rí.”

27. Àwọn ni ó bá Fáráò ọba Éjíbítì sọ̀rọ̀ nípa kíkó àwọn ará Ísírẹ́lì jáde kúrò ni Éjíbítì, àní Mósè àti Árónì yìí kan náà ni.

28. Nígbà tí Olúwa bá Mósè sọ̀rọ̀ ni Éjíbítì,

29. Ó ni “Èmi ni Olúwa. Sọ ohun gbogbo ti mo ti sọ fún ọ fún Fáráò ọba Éjíbítì.”

30. Ṣùgbọ́n Mósè sì wí ní iwájú Olúwa pé, “Níwọ̀n ìgbà ti mo jẹ́ akólòlò, ọ̀nà dà ti Fáráò yóò ṣe fi etí sí mi?”

Ka pipe ipin Ékísódù 6