Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 6:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà ní Olúwa sọ fún Mósè pé, “Ní ìsin yìí, ìwọ yóò rí ohun tí èmi yóò ṣe sí Fáráò pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá mi ni yóò fi jẹ́ kí wọn lọ; pẹ̀lú ọwọ́ agbára ńlá mi, òun yóò lé wọn jáde kúró ní orílẹ̀ èdè rẹ̀.”

2. Ọlọ́run sì tún sọ fún Mósè pé, “Èmi ni Olúwa.

3. Mo fi ara hàn Ábúráhámù, Ísáákì àti Jákọ́bù bí Ọlọ́run alágbára (Ẹ́lísàdáì) ṣùgbọ́n nípa orúkọ mi Olúwa, Èmi kò fi ara mi hàn wọ́n.

4. Èmí sì tún fi idi májẹ̀mu mi múlẹ̀ pẹ̀lú wọn láti fún wọn ní ilẹ̀ Kénánì, ilẹ̀ tí wọn gbé gẹ́gẹ́ bí àjòjì.

5. Èmi sì ti tún gbọ́ kíkùn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì àwọn tí àwọn ará Éjíbítì mú gẹ́gẹ́ bí ẹrú, àti pé èmi sì ti rántí májẹ̀mu mi.

6. “Sọ fún àwọn ará ilé Ísírẹ́lì: ‘Èmi ni Olúwa, Èmi yóò sọ yín di òmìnira kúró nínú àjàgà àwọn ará Éjíbítì. Èmi yóò sì gbà yín sílẹ̀ kúró ní oko ẹrú wọn. Èmi yóò dá a yín sílẹ̀ pẹ̀lú apá nínà (àwọn iṣẹ́ ìyanu) àti pẹ̀lú ìdájọ́ ńlá.

7. Èmi yóò mú un yín bí ènìyàn mi, èmi yóò sì jẹ̀ Ọlọ́run yín. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, ẹni tí ó mú un yín jáde kúró nínú àjàgà àwọn ará Íjíbítí.

8. Èmi yóò mú un yín wá ilẹ̀ náà ti èmi ti búra pẹ̀lú ìgbọ́wọ́sókè láti fi fún Ábúráhámù. Ísáákì àti Jákọ́bù. Èmi yóò fi fún un yín bí ohun ìní, èmi ni Olúwa.’ ”

9. Mósè sì sọ èyí fún àwọn ará Ísírẹ́lì, ṣùgbọ́n wọn kò fi etí sílẹ̀ sí Mósè nítorí ọkàn wọn tó rẹ̀wẹ̀sì àti nítorí ìgbékùn búburú bí ohun tí ó ti kọ́ sọ kó wọn sí ní oko ẹrú wọn.

10. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún Mósè.

11. “Lọ, sọ fún Fáráò ọba Éjíbítì pé kí ó jẹ́ kí àwọn ará Ísírẹ́lì lọ kúró ní orílẹ̀ èdè rẹ̀.”

12. Ṣùgbọ́n Mósè sọ fún Olúwa pé, “Nígbà ti àwọn ará Ísírẹ́lì tó jẹ́ ènìyàn mi kó fetí sí ọ̀rọ̀ mi, báwo ni Fáráò yóò se fetí sí ọ̀rọ̀ mi, nígbà ti mo jẹ́ akólòlò?”

Ka pipe ipin Ékísódù 6