Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 5:1-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn náà ni Mósè àti Árónì tọ Fáráò lọ, wọ́n sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ: ‘Jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi kí ó lọ, kí wọn kí ó lè ṣe àjọ mi ní ijù.’ ”

2. Fáráò dáhùn wí pé, “Ta ni Olúwa, tí èmi yóò fi gbọ́ràn sí i lẹ́nu, tí èmi yóò fi jẹ́ kí Ísírẹ́lì ó lọ? Èmi kò mọ Olúwa, èmi kò sì ní jẹ́ kí Ísírẹ́lì ó lọ.”

3. Lẹ́yìn náà ni wọ́n wí pé, “Ọlọ́run àwọn Hébérù tí pàdé wa. Ní ìsinsìnyìí, jẹ́ kí a lọ ní ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sínú ihà láti rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run wa, kí ó má ba á fi àjàkálẹ̀-àrùn tàbí idà bá wa jà.”

4. Ṣùgbọ́n ọba Éjíbítì sọ wí pé, “Mósè àti Árónì, èése ti ẹ̀yin fi mú àwọn ènìyàn kúrò lẹ́nu iṣẹ́ wọn? Ẹ padà sẹ́nu iṣẹ́ yín.”

5. Nígbà náà ni Fáráò sọ pé, “Ẹ wò ó àwọn ènìyàn náà ti pọ̀ sí ì nílẹ̀ yìí ní ìsinsìnyìí, ẹ̀yin sì ń dá wọn dúró láti máa bá iṣẹ́ lọ.”

6. Ní ọjọ́ yìí kan náà ni Fáráò pàṣẹ fún àwọn akóniṣiṣẹ́ àti àwọn ti ń ṣe alábojútó iṣẹ́ lórí àwọn ènìyàn.

7. “Ẹ̀yin kò ní láti pèsè koríko gbígbẹ fún bíríkì síṣun mọ́ fún àwọn ènìyàn wọ̀nyí; ẹ jẹ́ kí wọn máa wá koríko gbígbẹ fún ara wọn.

8. Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí wọn ó ṣe iye bíríkì kan náà bí ì ti àtẹ̀yìnwá, kí ẹ má ṣe dín iye rẹ̀ kú. Ọ̀lẹ ni wọ́n, ìwà ọ̀lẹ yìí náà ló mú wọn pariwo pé, ‘Ẹ jẹ́ kí a lọ, kí a sì rúbọ sí Ọlọ́run wa.’

9. Ẹ mú iṣẹ́ náà le fún wọn, kí wọn bá a le è tẹramọ́ iṣẹ́ wọn, ẹ má fi ààyè gba irọ́ wọn.”

10. Ní ìgbà náà ni àwọn akóniṣiṣẹ́ àti àwọn tí ń ṣe alábojútó iṣẹ́ jáde tọ̀ wọ́n lọ láti sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Èyí ni ohun tí Fáráò sọ, ‘Èmi kò ní fún un yín ni koríko gbígbẹ mọ́.

11. Ẹ lọ wá koríko gbígbẹ ni ibi tí ẹ bá ti lè rí i, ṣùgbọ́n iṣẹ́ yín kí yóò dínkù.’ ”

12. Gbogbo wọn sí fọ́n káàkiri ni ilẹ̀ Éjíbítì láti sa ìdì koríko tí wọn yóò lò bí ì koríko gbígbẹ fún sísun bíríkì.

Ka pipe ipin Ékísódù 5