Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 40:24-29 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Ó gbé ọ̀pá fìtílà sínú àgọ́ àjọ ní òkánkán tábìlì ní ìhà gúsù Àgọ́ náà.

25. Ó sì tan àwọn fítìlà náà níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún-un.

26. Mósè gbé pẹpẹ wúrà sínú Àgọ́ àjọ níwájú aṣọ títa

27. ó sì jó tùràrí dídùn lórí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún-un.

28. Ó sì ta aṣọ títa sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ náà.

29. Ó gbé pẹpẹ ẹbọ sísun sí ẹ̀gbẹ́ ẹnu ọ̀nà Àgọ́, àgọ́ àjọ, ó sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ oúnjẹ́ (ọkà), gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún-un.

Ka pipe ipin Ékísódù 40