Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 40:18-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Nígbà tí Mósè gbé Àgọ́ náà ró ó fi ihò ìtẹ̀bọ̀ sí ààyè rẹ̀, ó to pákó rẹ̀, ó fi ọ̀pá rẹ̀ bọ̀ ọ́, ó sì gbé àwọn òpó rẹ̀ ró.

19. Ó na aṣọ àgọ́ náà sórí Àgọ́, ó sì fi ìbòrí bo orí Àgọ́ náà, bí Olúwa ṣe pàṣẹ fún un.

20. Ó mu ẹ̀rí, ó sì fi sínú àpótí, ó so àwọn òpó mọ́ àpótí náà, ó sì fi àánú bo orí rẹ.

21. Ó sì gbé àpótí náà wá sínú àgọ́; ó sì sọ aṣọ títa, ó sì ta á bo àpótí ẹ̀rí, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún-un.

22. Mósè gbé tábìlì sínú àgọ́ àjọ sí ìhà àríwá àgọ́ náà lẹ́yìn aṣọ títa,

23. ó sì to àkàrà sórí rẹ̀ níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún-un.

24. Ó gbé ọ̀pá fìtílà sínú àgọ́ àjọ ní òkánkán tábìlì ní ìhà gúsù Àgọ́ náà.

25. Ó sì tan àwọn fítìlà náà níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún-un.

26. Mósè gbé pẹpẹ wúrà sínú Àgọ́ àjọ níwájú aṣọ títa

27. ó sì jó tùràrí dídùn lórí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún-un.

28. Ó sì ta aṣọ títa sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ náà.

29. Ó gbé pẹpẹ ẹbọ sísun sí ẹ̀gbẹ́ ẹnu ọ̀nà Àgọ́, àgọ́ àjọ, ó sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ oúnjẹ́ (ọkà), gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún-un.

30. Ó gbé agbada sí àárin àgọ́ àjọ àti pẹpẹ, ó sì pọn omi sínú rẹ̀ fún wíwẹ̀,

31. Mósè, Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ lò ó láti fi wẹ ọwọ́ àti ẹṣẹ̀ wọn.

32. Wọ́n máa ń wẹ̀ nígbàkugbà tí wọ́n bá wọ àgọ́ àjọ tàbí tí wọ́n bá súnmọ́ pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.

33. Mósè sì gbé àgbàlá tí ó yí Àgọ́ náà kà ró àti pẹpẹ, ó sì ta aṣọ títa ti ẹnu ọ̀nà sí àgbàlá náà. Bẹ́ẹ̀ Mósè ṣe parí iṣẹ náà

34. Nígbà náà ni àwọ̀ọsánmọ̀ bo àgọ́ àjọ, ògo Olúwa bo Àgọ́ náà.

35. Mósè kò sì lè wọ inú Àgọ́ àjọ, nítorí àwọ́ọ́sánmọ̀ wà lórí rẹ, ògo Olúwa sì ti kún inú Àgọ́ náà.

Ka pipe ipin Ékísódù 40