Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 40:14-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Mú àwọn ọmọ rẹ̀ kí o sì fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀ wọ́n.

15. Ta òróró sí wọn ní orí gẹ́gẹ́ bí o ti ta òróró sí baba wọn ńi orí, nítorí kì wọn lè máa sìn mi bí àlùfáà. Ìtasórí wọn yóò jẹ́ iṣẹ́ àlùfáà ti yóò máa lò fún gbogbo ìrandíran tó ń bọ̀.”

16. Mósè ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún-un.

17. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé Àgọ́ náà ró ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ìn-ní ní ọdún kejì.

18. Nígbà tí Mósè gbé Àgọ́ náà ró ó fi ihò ìtẹ̀bọ̀ sí ààyè rẹ̀, ó to pákó rẹ̀, ó fi ọ̀pá rẹ̀ bọ̀ ọ́, ó sì gbé àwọn òpó rẹ̀ ró.

19. Ó na aṣọ àgọ́ náà sórí Àgọ́, ó sì fi ìbòrí bo orí Àgọ́ náà, bí Olúwa ṣe pàṣẹ fún un.

20. Ó mu ẹ̀rí, ó sì fi sínú àpótí, ó so àwọn òpó mọ́ àpótí náà, ó sì fi àánú bo orí rẹ.

21. Ó sì gbé àpótí náà wá sínú àgọ́; ó sì sọ aṣọ títa, ó sì ta á bo àpótí ẹ̀rí, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún-un.

22. Mósè gbé tábìlì sínú àgọ́ àjọ sí ìhà àríwá àgọ́ náà lẹ́yìn aṣọ títa,

23. ó sì to àkàrà sórí rẹ̀ níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún-un.

24. Ó gbé ọ̀pá fìtílà sínú àgọ́ àjọ ní òkánkán tábìlì ní ìhà gúsù Àgọ́ náà.

25. Ó sì tan àwọn fítìlà náà níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún-un.

26. Mósè gbé pẹpẹ wúrà sínú Àgọ́ àjọ níwájú aṣọ títa

27. ó sì jó tùràrí dídùn lórí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún-un.

28. Ó sì ta aṣọ títa sí ẹnu ọ̀nà Àgọ́ náà.

29. Ó gbé pẹpẹ ẹbọ sísun sí ẹ̀gbẹ́ ẹnu ọ̀nà Àgọ́, àgọ́ àjọ, ó sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ oúnjẹ́ (ọkà), gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún-un.

30. Ó gbé agbada sí àárin àgọ́ àjọ àti pẹpẹ, ó sì pọn omi sínú rẹ̀ fún wíwẹ̀,

31. Mósè, Árónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ lò ó láti fi wẹ ọwọ́ àti ẹṣẹ̀ wọn.

32. Wọ́n máa ń wẹ̀ nígbàkugbà tí wọ́n bá wọ àgọ́ àjọ tàbí tí wọ́n bá súnmọ́ pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.

Ka pipe ipin Ékísódù 40