Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 40:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Olúwa sì wí fún Mósè pé:

2. Ní ọjọ́ kìn-ín-ní. Oṣù kìn-ín-ní ni kí ó gbé Àgọ́ náà, àgọ́ àjọ náà ró.

3. Gbé àpótí ẹ̀rí sí inú rẹ̀, kí ó sì bo àpótí náà pẹ̀lú aṣọ títa.

4. Gbé tábìlì náà wọ ilé, kí o sì tò àwọn ohun tí ó jẹ́ tirẹ̀ lé e lórí. Nígbà náà gbé ọ̀pá fìtílà wọlé, kí o sì to àwọn fìtílà rẹ̀.

5. Gbé pẹpẹ wúrà ti tùràrí sí iwájú àpótí ẹ̀rí, kí o sì fi aṣọ títa ẹnu ọ̀nà sí ara àgọ́ náà.

Ka pipe ipin Ékísódù 40