Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 39:4-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. Ó ṣe aṣọ èjìká fún ẹ̀wù èfòdì náà, èyí tí ó so mọ igun rẹ̀ méjèèjì, nítorí kí ó lè so pọ̀.

5. Ọnà ìgbànú híhun rẹ̀ rí bí i ti rẹ̀ ó rí bákan náà pẹ̀lú ẹ̀wù èfòdì ó sì sé e pẹ̀lú wúrà, àti pẹ̀lú aṣọ aláró, elésèé àlùkò, òdòdó àti pẹ̀lú ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pà sẹ fún Mósè.

6. Ó ṣìṣe òkúta óníkísì tí a tò sí ojú ìdè wúrà, tí a sì fín wọn gẹ́gẹ́ bí èdìdì pẹ̀lú orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì.

7. Ó sì so wọ́n mọ́ asọ èjìká ẹ̀wù èfòdì náà bí òkúta ìrántí fún àwọn ọmọ Isirẹli, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pà sẹ fún Mósè.

8. Ó ṣe iṣẹ́ ọnà sí igbáyà náà iṣẹ́ ọgbọ́n ọlọ́nà. Ó ṣe é bí, ẹ̀wù èfòdì: ti wúrà ti aṣọ aláró, ti elésèé àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára.

9. Igun rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ ṣe déédé ìwọ̀n ṣẹ̀ǹtímítà méjìlélógún ni gígùn rẹ̀, fífẹ̀ rẹ̀ náà sì jẹ́ ìwọ̀n sẹ̀ǹtímítà méjìlélógún ó sì jẹ́ ìsẹ́po méjì.

10. Ó sì to ìpele òkúta mẹ́rin oníyebíye sí i. Ní ipele kìn-in-ní ní rúbì wà, tapásì àti bérílù;

11. ní ipele kejì, túríkúóṣè, sáfírù àti émérálídì;

12. ní ipele kẹta, Jásínítì, ágátè àti amétístì;

13. ní ipele kẹ́rin, kárísólítì, oníkísì, àti jásípérì. Ó sì tò wọ́n ní ojú ìdè wúrà ní títò wọn.

14. Wọ́n jẹ́ òkúta méjìlá ọkan fún orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan, a fín ọ̀kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí èdìdì pẹ̀lú orúkọ ẹnikọ̀ọ̀kan ẹ̀yà méjèèjìlá.

Ka pipe ipin Ékísódù 39