Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 39:25-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

25. Ó sì ṣe ago kìkì wúrà, ó sì ṣo wọ́n mọ́ àyìká ìsẹ́tí àárin pomégíránátè náà.

26. Aago àti pomégíránátè kọjú sí àyíká ìsẹ́ti ọ̀já àmùrè láti máa wọ̀ ọ́ fún iṣẹ́ àlùfáà, bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.

27. Fún Árónì àti àwọn ọmọ rẹ, wọ́n ṣe àwọ̀tẹ́lẹ̀ ti ọ̀gbọ̀ dáradára tí iṣẹ́ alásọ híhun.

28. Àti fìlà ọ̀gbọ̀ dáradára, ìgbàrí ọ̀gbọ̀ àti aṣọ abẹ́ ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára.

29. Ọ̀já náà jẹ́ ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára, aṣọ aláró, elésèé àlùkò àti òdòdó iṣẹ́ alábẹ́rẹ́ bí Olúwa ṣe pàṣẹ fún Mósè.

30. Ó ṣe àwo, adé mímọ́, láti ara kìkì wúrà, wọ́n sì kọ̀wé sí i, gẹ́gẹ́ bí i ìkọ̀wé lórí èdìdì: “MÍMỌ́ SÍ Olúwa.”

31. Wọ́n sì so ọ̀já aláró mọ́ ọn láti ṣo ó mọ́ fìlà náà, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mósè.

32. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo iṣẹ́ àgọ́ náà, ti àgọ́ àjọ parí. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàsẹ fún Mósè.

33. Wọ́n sì mú tabánákù náà tọ Mósè wá: àgọ́ náà àti gbogbo ohun ọ̀sọ́ rẹ̀, ìkọ́ rẹ̀, pákó rẹ̀, ọ̀pá rẹ̀, òpó rẹ̀ àti àwọn ihò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀;

34. ìbòrí awọ àgbò tí a kùn ní pupa, ìbòrí awọ àti ìji àsọ títa;

35. àpótí ẹ̀rí pẹ̀lú àwọn òpó rẹ̀ àti ìbòrí àánú;

Ka pipe ipin Ékísódù 39