Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 39:10-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

10. Ó sì to ìpele òkúta mẹ́rin oníyebíye sí i. Ní ipele kìn-in-ní ní rúbì wà, tapásì àti bérílù;

11. ní ipele kejì, túríkúóṣè, sáfírù àti émérálídì;

12. ní ipele kẹta, Jásínítì, ágátè àti amétístì;

13. ní ipele kẹ́rin, kárísólítì, oníkísì, àti jásípérì. Ó sì tò wọ́n ní ojú ìdè wúrà ní títò wọn.

14. Wọ́n jẹ́ òkúta méjìlá ọkan fún orúkọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ̀ọ̀kan, a fín ọ̀kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí èdìdì pẹ̀lú orúkọ ẹnikọ̀ọ̀kan ẹ̀yà méjèèjìlá.

15. Fún igbáyà náà, wọ́n ṣe ẹ̀wọ̀n iṣẹ́ kìkì wúrà, gẹ́gẹ́ bi okùn.

16. Wọ́n sì ṣe ojú ìdè wúrà méjì àti òrùka wúrà méjì, wọ́n sì so àwọn òkúta náà mọ́ igun méjèèjì igbáàyà náà.

17. Wọ́n sì so ẹ̀wọ̀n wúrà méjèèjì náà mọ́ àwọn òrùkà náà ni igun igbáàyà náà,

18. àti ní àwọn òpin ẹ̀wọ̀n tókù ni wọ́n fi mọ ojú ìdè méjèèjì, wọ́n so wọ́n mọ́ aṣọ èjìká ẹ̀wù èfòdì náà ní iwájú.

19. Wọ́n ṣe òrùka wúrà méjì, wọ́n sì so wọ́n mọ́ igun méjèèjì igbáyà náà ní etí tí ó wà ní inú lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹ̀wù èfòdì náà.

20. Wọ́n sì tún ṣe òrùka wúrà méjì sí i, wọ́n sì so wọ́n mọ́ ìdí aṣọ èjìká ní iwájú ẹ̀wù èfòdì náà tí ó sún mọ́ ibi tí a ṣe lọ́sọ̀ọ́ ní òkè ìgbànú ẹ̀wù èfòdí náà.

Ka pipe ipin Ékísódù 39