Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 38:24-31 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Àròpọ̀ iye wúrà lára wúrà ọrẹ tí a lò fún gbogbo iṣẹ́ ibi mímọ́ náà jẹ́ tálẹ́ńtì mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) àti ẹgbẹ̀rin (730) sékélì gẹ́gẹ́ bí i sékélì ibi mímọ́.

25. Sílífà tí a rí nínú ìjọ, ẹni tí a kà nínú ìkànìyàn jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) talẹ́ntì àti òjìlélẹ́gbẹ̀sán ó lé mẹ́ẹ̀dógún sékélì (1,775) gẹ́gẹ́ bí sékélì ibi mímọ́

26. ìwọ̀n gíráàmù márùn-ún ààbọ̀ (5. 5 grams) lórí ẹnìkọ̀ọ̀kan, gẹ́gẹ́ bí sékélì ibi mímọ́, lórí olúkúlùkù ẹni tí ó ti kọjá tí a ti kà, láti ẹni ogún ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ, àròpọ̀ wọ́n jẹ́ ọgbọ̀n-ọ̀kẹ́-lé-ẹgbẹ̀tadínlógún-ó-lé-àádọ́jọ ọkùnrin (603,550 men).

27. Ọgọ́run-ún talẹ́ntì fàdákà ní a lò láti fi dá ihò ìtẹ̀bọ̀ fún ibi mímọ́ àti fún aṣọ títa ọgọ́rùnún ihò ìtẹ̀bọ̀ nínú ọgọ́rùn-ún talẹ́ntì náà talẹ́ntì kan fún ihò ìtẹ̀bọ̀ kọ̀ọ̀kan.

28. Ó lo òjìdínlẹ́gbẹ̀san ó lé mẹ́ẹ̀dogun sékélì (1,775 shekels) ìwọ̀n ogún gíráàmù ni ó fi ṣe ìkọ́ fún òpó náà, láti fi bo orí òpó náà àti láti fi ṣe ìgbànú wọn.

29. Idẹ ara ọrẹ náà jẹ́ àádọ́rin tálẹ́ntì àti egbèjìlá sékélì (2,400 shekels).

30. Ó lò ó láti fi ṣe ihò ìtẹ̀bọ̀ fún ẹnu ọ̀nà àgọ́ àjọ, pẹpẹ idẹ náà pẹ̀lú àrò idẹ rẹ̀ àti gbogbo ohun èlò rẹ̀,

31. ihò ìtẹ̀bọ̀ fún àyíká àgbàlá náà àti èyí tí ó wà fún ẹnu ọ̀nà àti gbogbo èèkàn àgọ́ náà fún tabánákù àti èyí tí ó wà fún àyíká àgbàlá náà.

Ka pipe ipin Ékísódù 38