Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 38:15-25 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. àti aṣọ títa ní ìhà kejì tí ó wà lẹ́nu ọ̀nà àgbàlá náà jẹ́ mítà mẹ́fà ààbọ̀ (6. 9 meters) pẹ̀lú òpó mẹ́ta àti ihò ìtẹ̀bọ̀ mẹ́fà.

16. Gbogbo aṣọ tí ó yí àgbàlá náà jẹ́ ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára.

17. Ihò ìtẹ̀bọ̀ fún òpó náà idẹ ni. Ìkọ́ òpó náà àti ìgbànú tí ó wà lára òpó náà jẹ́ fàdákà, a sì bo orí wọn pẹ̀lú fàdákà; gbogbo àwọn òpó àgbàlá náà ní ìgbànú fàdákà.

18. Aṣọ tita fún ẹnu ọ̀nà àgbàlá náà jẹ́ ti aṣọ aláró, ti elésèé àlùkò, ti òdòdó àti ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára iṣẹ́ alábẹ́rẹ́ ni. Ó jẹ́ mítà mẹ́sàn-án ní gígùn (9 meters), gẹ́gẹ́ bí aṣọ títa àgbàlá náà, àti gíga rẹ̀ jẹ mítà méjì (2. 3 meters),

19. pẹ̀lú òpó mẹ́rin àti ihò ìtẹ̀bọ̀ idẹ mẹ́rin. Ìkọ́ àti ìgbànú wọn jẹ́ fàdákà, a sì bo orí wọn pẹ̀lú fàdákà.

20. Gbogbo èèkàn àgọ́ tabánákù náà àti ti àyíká àgbàlá náà jẹ́ idẹ.

21. Wọ̀nyí ni iye ohun èlò tí a lò fún tabánákù náà, tabánákù ẹ̀rí, èyí ti a kọ bí òfin Mósè nípa àwọn ọmọ Léfì ní abẹ́ àkóso Itamari ọmọ Árónì àlùfáà.

22. (Bésálélì ọmọ Úrì, ọmọ Húrì, ti ẹ̀yà Júdà, ṣe ohun gbogbo ti Olúwa pàṣẹ fún Mósè;

23. Pẹ̀lú rẹ̀ ni Óhólíábù ọmọ Áhísámákì, ti ẹ̀yà Dánì-alágbẹ̀dẹ́, àti oníṣẹ́ ọnà àti oníṣọ̀nà iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ní aṣọ aláró àti elésèé àlùkò àti òdòdó àti ọ̀gbọ̀ dáradára.)

24. Àròpọ̀ iye wúrà lára wúrà ọrẹ tí a lò fún gbogbo iṣẹ́ ibi mímọ́ náà jẹ́ tálẹ́ńtì mọ́kàndínlọ́gbọ̀n (29) àti ẹgbẹ̀rin (730) sékélì gẹ́gẹ́ bí i sékélì ibi mímọ́.

25. Sílífà tí a rí nínú ìjọ, ẹni tí a kà nínú ìkànìyàn jẹ́ ọgọ́rùn-ún (100) talẹ́ntì àti òjìlélẹ́gbẹ̀sán ó lé mẹ́ẹ̀dógún sékélì (1,775) gẹ́gẹ́ bí sékélì ibi mímọ́

Ka pipe ipin Ékísódù 38