Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 37:3-20 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

3. Ó sì dá òrùka wúrà mẹ́rin fún un, ó so wọ́n mọ́ ẹṣẹ̀ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, pẹ̀lú òrùka méjì ní ìhà kìn-ín-ní àti òrùka méjì ni ìhà kejì.

4. Ó sì tún ṣe òpó igi kaṣíà, ó sì bò wọ́n pẹ̀lú wúrà.

5. Ó sì kó àwọn òpó náà sínú òrùka ní ìhà àpótí náà láti máa fi gbé e.

6. Ó se ìbòrí àánú kìkì wúrà ìgbọ̀nwọ́ méjì àti ààbọ̀ gígùn rẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni fífẹ̀ rẹ̀.

7. Ó sì se kérúbù méjì láti inú òlù wúrà ní òpin ìbòrí náà.

8. Ó se kérúbù kan ni òpin èkínní, ó sì tún ṣe kérúbù kejì sí èkejì; ní òpin méjèèjì ó ṣe ìtẹ́ àánú ìbòrí wọn.

9. Àwọn kérúbù sì na ìyẹ́ apá wọn sókè sí i, ó fi ìji bo ìbòrí wọn. Àwọn kérúbù kọjú sí ara wọn, wọ́n ń wo ìbòrí náà.

10. Ó se tábìlì igi kaṣíá ìgbọ̀nwọ́ méjì ní gígùn, ìgbọ̀nwọ́ kan ní fífẹ̀, àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní gíga.

11. Ó sì fi kìkì wúrà bòó, ó sì se ìgbátí yí i ká.

12. Ó sì tún ṣe etí ìbù ọwọ́ fífẹ̀ yìí ká, ó sì fi ìgbátí wúrà yí etí rẹ̀ ká.

13. Ó sì dá òrùka wúrà fún tábìlì náà, ó sì so wọ́n mọ́ igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, níbi tí ẹṣẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wà.

14. Àwọn òrùka náà wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ etí rẹ̀ láti gbá àwọn òpó náà mu láti máa fi gbé tábìlì náà.

15. Igi kaṣíá ni ó fi se òpó ti a fi ń gbé tábìlì náà, ó sì fi wúrà bò ó.

16. Ó sì ṣe àwọn ohun èlò tí ó wà lórí tábìlì náà ní kìkì wúrà, abọ́ rẹ̀, àwo rẹ, àwokòtò rẹ̀ àti ìgò rẹ̀ fún dída ọrẹ mímu jáde.

17. Ó sì se ọ̀pá fìtílà náà ní kìkì wúrà ó sì lù ú jáde, ọ̀pá rẹ̀, ìtànná ìfẹ́ rẹ̀, irudi rẹ àti ago rẹ̀, wọ́n jẹ́ òkan náà.

18. Ẹ̀ka mẹ́fà ní ó jáde láti ìhà ọ̀pá fìtílà náà mẹ́ta ní ìhà àkọ́kọ́ àti mẹ́ta ní ìhà èkejì.

19. Kọ́ọ̀bù mẹ́ta ni a se bí ìtànná alímóndì pẹ̀lú ìrùdí àti ìtànná wà ni ẹ̀ka kan, mẹ́ta sì tún wà ní ẹ̀ka mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni ní ẹ̀ka mẹ́fẹ̀ẹ̀fà jáde lára ọ̀pá fìtílà.

20. Lára ọ̀pá fìtílà náà ni a se kọ́ọ̀bù mẹ́rin bí ìtànná alímóndì, ìrùdí rẹ̀ àti ìtànná rẹ̀:

Ka pipe ipin Ékísódù 37