Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ékísódù 35:27-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

27. Àwọn olórí mú òkúta óníkísì wá láti tò ó lórí ẹ̀wù éfódì àti igbáàyà.

28. Wọ́n sì tún mú olóòrùn àti òróró ólífì wá fún títanná àti fún òróró ìtasórí àti fún tùràrí dídùn.

29. Gbogbo àwọn ènìyàn Isirẹli ọkùnrin àti obìnrin ẹni tí ó fẹ́ mú ọrẹ àtinúwá fún Olúwa fún gbogbo iṣẹ́ tí Olúwa ti pa láṣẹ fún wọn láti se nípaṣẹ̀ Mósè.

30. Nígbà náà ni Mósè wí fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, “Wò ó, Olúwa ti yan Bésálélì ọmọ Úrì, ọmọ Húrì, ti ẹ̀yà Júdà,

31. Ó sì ti fi ẹ̀mí Ọlọ́run kún-un, pẹ̀lú ọgbọ́n, agbára, ìmọ̀ àti gbogbo onírúurú isẹ́ ọnà

32. Láti má a se aláràbarà iṣẹ́ ní ti wúrà, fàdákà àti idẹ,

33. láti gbẹ́ òkúta àti láti tò ó, láti fún igi àti láti sísẹ ni gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà.

34. Ó sì fún òun àti Óhólíábù ọmọ Áhísámákì ti ẹ̀yà Dánì, ni agbára láti kọ́ àwọn tókù.

35. Ó sì fi ọgbọ́n kún wọn láti se gbogbo onírúurú iṣẹ́, ti oníṣọ̀nà, ti ayàwòrán, ti aránsọ, ti alásọ aláró, ti elésèé àlùkò, ti òdòdó àti ní ọ̀gbọ̀ dáradára àti ti ahunsọ, gbogbo èyí tí ọ̀gá onísẹ́ ọnà àti ayàwòrán ń ṣe.

Ka pipe ipin Ékísódù 35